Ọkọ̀ bọ́ọ̀sì akẹ́kọ̀ọ́ gbiná, Àwọn ọmọdé tó lé ní ogún jóná ráúráú
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọkọ̀ bọ́ọ̀sì kan tó gbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ̀ alákọ̀bẹ́ẹ̀rẹ̀ kan ti gbiná lásìkò ìjàmbá ọkọ̀ kan tó wáyé ní ìlú Bangkoko tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀èdè Thai.
Awọn ọmọde mẹrindinlogun ati olukọni mẹta ni ori ko yọ ninu ijamba naa; amọṣa awọn akẹkọọ mejilelogun ati olukọni mẹta ni wọn ko ri mọ bayii, gẹgẹ bi minisita fun igbokegbodo ọkọ lorilẹede naa ṣe sọ.
Olootu ijọba orilẹede Thailand ṣalaye pe ijamba ọkọ naa lo ṣokunfa “iku ati ifarapa” – amọṣa wọn ko tii le sọ ni pato iye awọn eeyan to ku ninu ijamba ọkọ naa.
Awọn aworan to jade sita fihan bi ina ṣe jo ọkọ bọọsi naa patapata. Gẹgẹ bi ohun ti awọn ileeṣẹ iroyin abẹle lorilẹede naa sọ, awọn oluwadii ko ri aye wọ inu ọkọ naa nitori gbigbona ọkọ naa.
Mọkandinlogun ninu awọn ti ori ko yọ ninu ijamba ọkọ naa ti wa ni ile iwosan.
Ọkọ bọọsi to jona naa jẹ ọkan lara ọkọ bọọsi mẹta ti o n ko awọn ọmọde atawọn olukọ wọn nigba ti wọn n bọ nibi eto ijade abẹwo kan ti ile ẹkọ wọn ṣeto fun wọn lọ si ẹkun ariwa agbegbe Uthai Thani.
Minisita fun igbokegbodo ọkọ lorilẹede naa, Suriyahe Juangroongruangkit sọ pe afẹfẹ gaasi kan to lewu pupọpupọ ni wọn ṣe ohun amuṣagbara fun ọkọ bọọsi naa.
“Iṣẹlẹ to bani ninujẹ gidi ni iṣẹlẹ yii, bẹẹni ijọba yoo wa gbogbo ọna lati rii pe iru awọn ọkọ akero bayii ko lanfani lati lo irufẹ ohun amuṣagbara bayii nitori ọpọ ewu lo rọ mọ ọ.
Olootu ijọba orilẹede naa Paetongtarn Shinawatra sọ peijọba ni yoo san owo itọju gbogbo awọn eeyan to farapa ninu ijamba naa ti yoo si ṣe ẹtọ gba maa binu fun awọn to pa ipo da.
Piyalak Thinkaew, to n dari eto wiwa awọn eeyan to wa ninu ijamba naa ṣalaye pe awọn to ku ninu ijamba ọkọ to gbina naa jona to bẹẹ gẹ ti ẹnikẹni ko lee da wọn mọ rara.
Opopona marosẹ kan to wọ ilu Bangkok ni ọkọ bọọsi naa n gba nigba ti taya rẹ ṣa dede fọ, to si mu ko lọ kọlu irin idaabobo to yii opopona naa ki ina to sọ ni iwaju rẹ.
Iroyin sọ pe awakọ to wa ọkọ naa ti sa lọ, bi o tilẹ jẹ wi pe awọn alaṣẹ ti sọ pe wọn yoo waa jade nibikibi to ba pamọ si.
Ọjọ ori awọn akẹkọọ to wa ninu ọkọ ti ijamba ko yii ko tii kan si araye, amọṣa laarin ọdun mẹta si marundinlogun ni ọjọ ori awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa.
Orilẹede Thailand wa lara awọn orilẹede ti iṣẹlẹ ijamba ọkọ ti kere julọ lagbaye.
