Ohun tí ò̩pò̩ kò mò̩ nípa Oníwàásí àgbáyé nnì , Sheik Muyideen Ajani Bello
Fẹ́mi Akínṣọlá
Bá a pẹ́ láyé bíi kánrin, bá a gùn lẹ́mì í bí okùn tó gùn gùn gùn, bíkú bádé gbogbo ìgbìyànjú ọlọ́gbọ́n á dòmùgọ̀.
Àrùn ló gbọ wíwò, a ò rí ti olọ́jọ́ ṣe.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bàbá ọ̀hún kìí ṣe ọmọdé, nítorí ó ti lé lẹni ọgọ́rin ọdún dáadáa, síbẹ̀, agbọ́-sọgbá -nù ni ikú àgbà oníwàásí tí gbogbo èèyàn mọ̀ bíi ẹni mowó nnì, Sheik Muideen Ajani Bello jẹ́ fún gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́ pé ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn táwọn Mùsùlùmí máa n fẹ́ràn wàásí rẹ̀ náà ti jáde láyé.
Titi ta a fi n ko iroyin yii jọ, ko ti i sẹni to mọ ohun to ṣokunfa iku baba to fi ilu Ibadan ṣebugbe ọhun.
Bo tilẹ jẹ pe o nira fun ọpọ awọn ololufẹ baba ọhun lati gbagbọ, sibẹ, ọpọ awọn to sun mọ baba agba oniwaasi yii ni wọn ti n gbe e sori ayelujara wọn, ti wọn si ti n daro iku baba agba naa.
Kaakiri origun mẹrẹẹrin ilẹ Yoruba, to fi mọ ilẹ Hausa, ni wọn ti mọ baba oniwaasu naam nitori gbogbo ibẹ ni wọn ti maa n pe e pe ko waa ṣe waasi. Lasiko aawẹ ni aọn eeyan si maa n gbadun rẹ ju pẹlu awọn waasi iṣiti ọrọ ikilọ ati awọn ẹkọ kuraani to maa n jade lati ẹnu rẹ.
Ọdun 1940 ni wọn bi i sinu mọlẹbi Alaaji Bello Ajani ati Ubaidat Ajani Bello, ti agboole Arolu, Ita Olukoyi, niluu Ibadan.
Ileewe alakọọbẹrẹ ICD, Elekurọ ni Babab Muheedeen ti kawe alakọọbẹrẹ, ibẹ naa lo si ti ka girama. Ọmọọdun mẹwaa ni Muyedeen Bello wa to ti fifẹ han si ẹkọ alukuraani, to si ti n waasu kaakiri origun mẹrẹẹrin Ibadan.
Ileewe ẹkọ kewu ti wọn n pe ni Mahdul Arabiy to wa ni Elekurọ lo lọ laarin ọdun 1963 si 1967.
O ti kọ ẹkọ gẹgẹ bii olukọ imọ Islam lawọn ileewe kaakiri nilẹ Yoruba ati nilẹ Hausa, oun si ni Miṣọna Ansar-un-deen.
