NNPCL kéde iye tí lítà epo bẹtiró yóò jẹ́ báyìí ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan
Fẹ́mi Akínṣọlá
Kò sí bojúbojú níbẹ̀ mọ́,
Àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ epo bẹntiróòlù ní Náìjíríà, NNPCL ti kéde yanya báyìí iye tí wọ́n yóò máa ta epo bẹntiró tí wọ́n rà lọ́wọ́ iléeṣẹ́ Dangote.
NNPCL nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ wọn, Olufemi Soneye fi léde lórí ẹ̀rọ ayélujára X lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Kẹsàn-án ní iye tí àwọn máa ta epo náà wà ní ìbámu pẹ̀lú iye tí epo jẹ́ nínú oṣù náà.
Àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé N950 NNPCL yóò máa lítà epo kan ní ìpínlẹ̀ Eko, tí wọ́n yóò sì máa tà á ní N1,019 ní àwọn ìpínlẹ̀ tó jínà bíi Borno, Yobe, Adamawa àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ní ìpínlẹ̀ Oyo, Osun, Kwara àti àwọn ìpínlẹ̀ tó yíiká, NNPCL kéde pé N960 ni àwọn yóò máa ta lítà kan níbẹ̀.
N980.22 ni wọ́n ní títa lítà epo bẹntiró Dangote yóò jẹ́ ní ìpínlẹ̀ Rivers, Bayelsa, Akwa Ibom àtàwọn ìpínlẹ̀ ní ẹkùn ààrin gbùngùn gúúsù Nàìjíríà.
Àtẹ̀jáde náà fi kun pé N999.22 ni wọn yóò máa ta lítà epo kan ní Abuja, Kaduna, Kano, Plateau, Nasarawa, Niger.
Soneye nínú àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé ìjọba kọ́ ló ń sọ iye tí owọ bẹntiró yóò jẹ́ bíkòṣe ìdúnàádúrà láàrin àwọn tó ń ta epo àti iye tí wọ́n bá rà á.
Ó fi kún-un pé epo bẹntiróòlù tí àwọn gbé láti iléeṣẹ́ Dangote lọ́jọ́ Àìkú jẹ́ èyí tí àwọn fi owó dọ́là rà.
Ó ní ọjọ́ Kìíní, oṣù Kéwàá ni àwọn máa bẹ̀rẹ̀ òwò títa àti ríra epo pẹ̀lú Náírà.
Ó ṣàlàyé pé tí iléeṣẹ́ Dangote bá jiyàn àgbéjáde iye tí àwọn ra epo lọ́wọ́ wọn àti láti máa ta epo náà, inú àwọn yóò dùn bí wọ́n bá le yọ kúrò nínú owó náà fún àwọn.
NNPCL àti Dangote kò gbọ́ra wọn yé lórí iye epo bẹntiró
Ṣáájú ni NNPCL kéde pé N898 ni Dangote ta lítà epo bẹntiróòlù fún àwọn àmọ́ tí Dangote gbé àtẹ̀jáde kan jáde pé irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ọ̀rọ̀ náà.
Dangote ní àwọn kò ta epo fún NNPCL ní N898 nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi sórí ẹ̀rọ ayélujára X wọn àmọ́ wọn kò sọ iye tí wọ́n ta epo náà ní pàtó.
Èyí ló mú kí àwọn ọmọ Nàìjíríà náà máa bèèrè lọ́wọ́ Dangote pé èló gan-an ló tà á fún NNPCL àti pé kí wọ́n fi iye náà léde fọ́mọ Nàìjíríà.
Lẹ́yìn rẹ̀ ni NNPCL gbé iye tí wọ́n yóò máa ta epo náà fún ará ìlú jáde ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé.
