Lórí ìṣòro Nàìjíríà, Ọkọ ọ̀ mi kì í ṣe òpìdán, àmọ́ yóó gbìyánjú —Oluremi Tinubu
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní ìwọ̀n oníwọ̀n la kìí mọ̀, ó yẹ kí á mọ tẹni.
Aya Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Sẹ́nẹ́tọ̀ Olurẹmi Tinubu sọ pé ọkọ òun Ààrẹ Bọla Tinubu kìí ṣe pidán-pidán, ṣùgbón ó ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ láti jẹ́ kí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà padà bọ̀ sípò.
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ ni ilé ìjosìn kan níbi tí wọ́n ti n ṣe ayẹyẹ àyájọ́ ọdún òmìnira ní ìlú Abuja lánàá ọjọ́ Àìkú, Olurẹmi sọ pé ọkọ òun kò ní dẹ̀bi ohun tó bàjẹ́ ní Naijiria ru àwọn tó ti ṣe ìjọba sẹ́yìn.
Àmọ́ṣá, Oluremi ní ìjọba Tinubu yóó tún gbogbo ohun tó ti bàjẹ́ ṣe, àti pé yóó mú ìrọ̀rùn bá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíría .
Ó fikún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun ní ìgbàgbọ̀ nínú ọkọ òun pé ó máa ṣiṣẹ́ láti ríi pé àlàáfíà yóó fi jọba ni Nàìjíríà.
Sẹ́nẹ́tọ̀ Oluremi tún sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ọjọ́ ọ̀la sì ń bọ̀ wá dára lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ìgbà ọ̀pọ̀ ti dé ní Nàìjíríà, nítorí náà, àwọn ọmọ Nàìjíríà gbọdọ̀ rí ju ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ báyìí lọ tí wọ́n bá fẹ́ jẹ́ alábàápín nínú ìgbéga orílẹ-èdè wọn.
Ó sì tún rọ àwọn ọmọ orílẹ-èdè Nàìjíríà láti ṣe àjọyọ òmìnira ní ìṣọ̀kan èyí tó ń gbé orílẹ-èdè lékè.
”Kò sí ìdojúkọ tí a kò lè borí tí a bá lè tẹ lé ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ nínú ìwé mímọ́ pé ẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ tí a di ẹrù wúwo lé lórí, emi ó sì fi ìsinmi fún ọkàn yín.
Ní irú àsìkò báyìí, gbogbo ohun tí a lè ṣe ni láti di ìgbàgbọ́ wa mú sinsin nínú Ọlọ́run.
Aya Ààrẹ tún fi dá àwọn ọmọ orílẹ-èdè Nàìjíríà lójú pé Tinubu ti ké sí àwọn orílẹ̀-èdè lágbayé láti wá dá ilé iṣẹ́ sílẹ̀ fún ìrọ̀rún gbogbo èèyàn,” Olurẹmi sọ bẹ́ẹ̀.
