Ìdí tí mo fi lọ sí ibi ètò ‘America’s Got Talent’ – Josh2funny

Ìdí tí mo fi lọ sí ibi ètò ‘America’s Got Talent’ – Josh2funny

Mary Fágbohùn

Gbajumo aderin-in-posonu Naijiria, Josh Alfred, ti a mo si Josh2Funny, ti safihan pe  kikopa oun lori eto mohunmaworan ni, Amerika ni ebun (America’s Got Talent), kii se lati dije fun ebun sugbon lati safihan ebun ti oun ni.

E ranti pe Josh2Funny eni ti a mo fun fonran alawada idanwo afenuka ti o n se, gbe ebun re lo lati sere ni itage ti o tobi ju lagbaye, Amerika ni ebun (America’s Got Talent), laipe yi.

Gege bi o se so, awon asagbekale eto naa fi iwe pe e wa sibe lati mu ki awon oluworan rerin arin takiti.

Onifonran naa so eyi ninu iforo-wani-lenu-wo kan to se pelu iwe irohin Punch.

O wi pe, “Won pe mi wa si ori eto naa lati se nnkan ti mo se. Mo lo sibe lati lo safihan ‘Josh2funny’, eyi to je ohun ti awada mi da le lori.”

Aderin-in-posonu eni odun mejilelogbon naa mu ki awon oluworan rerin arin gbokiti pelu ere meta ti o se bii eni to yara ka iwe ju, eni to le yara soro orin ni kiakia ju ati pidanpidan lori eto naa.

Bo ti le je pe awon kan lara awon adajo lori eto naa ni ere alawada re daru mo oun loju ti won si fun ni “rara” ni igba meteeta, Simon fun Josh ni “bee ni” ninu igbiyanju re to se keyin, ti o si gboriyin fun imose awada re.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *