Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ní etí omi ìkìlọ̀ rè é o! – NEMA ṣèkìlọ̀
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé àwọn àgbà ní a wí fúnni ká tó dáni, àgbà ìjàdkàdì ni. Wọ́n sì ní ó n bọ̀,ó n bọ̀, àwọ̀n láà dẹ ẹ́ dèé .
Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, NEMA ti ṣèkìlọ̀ pé ó ṣeéṣe kí omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù tún ṣọṣẹ́ gidigidi láìpẹ́ yìí nítorí bí orílẹ̀ èdè Cameroon ṣe fẹ́ ṣí omi odò Lagdo wọn sílẹ̀.
NEMA ní àwọn ìpínlẹ̀ tó wà ní bèbè omi odò Benue àti River ní ó ṣeéṣe kí àgbàrá náà ṣe ìjàmbá fún jùlọ tí wọ́n sì pàrọwà sí àwọn ènìyàn tó ń gbé létí odò náà láti kúrò níbẹ̀ lásìkò yìí.
Wọ́n ní ó kéré tán ìpínlẹ̀ mọ́kànlá bíi Adamawa, Taraba, Benue, Nasarawa, Kogi, Anambra, Edo, Delta, Bayelsa, Rivers àti Cross Rivers ni ó ṣeéṣe kí wọ́n fara kásá ìjàmbá omíyalé náà.
Ní ọdún tó kọjá, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àti dúkìá ló ṣòfò ní Nàìjíríà sọ́wọ́ omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù lẹ́yìn tí orílẹ̀ èdè Cameroon ṣí odò Ladgo kan náà sílẹ̀.
Dókítà Mustapha Habeeb tó jẹ́ adarí àjọ NEMA sọ fún akòròyìn pé àwọn aláṣẹ ní orílẹ̀ èdè Cameroon ti fi tó àwọn létí pé díẹ̀díẹ̀ ni àwọn yóò máa ṣí odò náà.
Dókítà Habbeb ní àwọn ti fi ìròyìn náà tó àwọn òṣìṣẹ́ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ Kogi, Benue àti Niger láti wà ní ìgbáradì dáadáa nítorí àwọn ni ọ̀rọ̀ yóò kọ́kọ́ kàn tí wọ́n bá ṣí odò náà.
Ó ṣàlàyé pé àwọn ti ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan tí ọ̀rọ̀ náà kan láti ṣàlàyé fún wọn ohun tí orílẹ̀èdè Cameroun sọ fún àwọn.
Ó ní lẹ́yìn náà ni òun tún sọ fún wọn níbi ìpàdé ìgbìmọ̀ aláṣẹ orílẹ̀èdè yìí láti gbáradì, kí wọ́n sì pèsè àmójútó tó péye sílẹ̀ kí odò náà má baà ṣe àkóbá tó lágbára fún àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ wọn.
Bákan náà ló ní òun gbà wọ́n ní ìmọ̀ràn láti pèsè ohun èlò láti mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan àti ní àwọn ẹkùn kọ̀ọ̀kan wọn.
Habeeb fi kún un pé àwọn gómìnà gbọ́dọ̀ ṣe àmójútó gbogbo ojúṣan àgbàrá wọn àti àwọn ibi tí omi ń gbà kọjá ní agb]egbè wọn kí ètò náà tó bẹ̀rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ náà ní iléeṣẹ́ tó ń mójútó ọ̀rọ̀ omi àti ìmọ́tótó ti fi ìkọnilóminú hàn lórí bí odò River Benue ṣe ti kún ní àkúnjù tó sì rọ àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ tó wà ní agbègbè omi yìí láti tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá.
Ní ọdún tó kọjá àwọn aláṣẹ ní Nàìjíríà ní ó kéré tán ènìyàn 1,500 ló farapa, tí 500 mìíràn sì pàdánù ẹ̀mí wọn sí omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù ní Nàìjíríà.
Àwọn ènìyàn tó di aláìnílé lórí lọ́dún tó kọjá lé ní mílíọ̀nù kan lẹ́yìn tí Cameroon ṣí odò Lagdo ọ̀hún kan náà.
Àwọn ìpínlẹ̀ mọ́kànlá tó pààlà pẹ̀lú odò náà ni ó sì ti ṣe àkóbá fún lọ́pọ̀lọpọ̀.
Kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí NEMA yóò máa kìlọ̀ omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù fún àwọn ìpínlẹ̀ tí ó le ṣe àkóbá fún.
Ní oṣù Kọkànlá ọdún 2022 ni àjọ náà ti kọ́kọ́ kìlọ̀ pé omíyalé yóò pọ̀ ní àwọn ìpínlẹ̀ kan lọ́dún 2023 gẹ́gẹ́ bó ṣe wáyé lọ́dún 2022.
Wọ́n fẹ̀sùn kan pé àwọn ìpínlẹ̀ kan kò kọbi ara sí ìkìlọ̀ tí àwọn ṣe lórí ọ̀rọ̀ omíyalé náà.
Adarí NEMA, nígbà tó yọjú níwájú ìgbìmọ̀ àjọ tó ń rí sí àwọn àkàṣe iṣẹ́ kọminú pé gbogbo ìkílọ̀ tí àwọn ṣe fún àwọn ìpínlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2022 ni wọn kò múlò rárá.
Ó ní bí àwọn ìpínlẹ̀ náà ṣe kọtí ọ̀gbọ̀in sí àwọn ìpínlẹ̀ náà lọ ṣokùnfà bí omíyalé tó wáyé ní 2022 ṣe ṣàkóbá púpọ̀.
Ṣaájú ni NEMA ti ṣèkìlọ̀ pé àwọn ìpínlẹ̀ m;ejìlélọ́gbọ̀n máa rí ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù nítorí àyípadà ojú ọjọ́.
