Ẹlẹ́wọ̀n sálọ kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ìlú Maiduguri
Nigerian Correctional
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní èèyàn tó bá n wá nnkan kìí dákẹ́ ìbòòsì. Èyí ló bí igbe tí Iléeṣẹ́ tó n rí sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ni Nàìjíríà, NCS, pa síta pé ẹlẹ́wọ̀n 281 làwọn ṣì n wá báyìí lẹ́yìn tí wọ́n sálọ kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ìlú u Maiduguri.
NSC ni iṣẹlẹ naa lo waye latari bi awọn ṣe ko awọn ẹlẹwọn kuro lọgba ẹwọn naa nitori iṣẹlẹ omiyale to mi ilu Maiduguri titi.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣe naa, Umar Abubakar fi lede lọjọ Aiku lo ti kede bẹẹ.
Abubakar sọ pe “ileeṣẹ Nigerian Correctional Service mọ nipa iṣẹlẹ omiyale to kọlu ilu Maiduguri, nipinlẹ Borno, atawọn ilu mii lagbegbe rẹ.
“O ṣeni laanu pe iṣẹlẹ yii ti da wahala silẹ ni bo ṣe wo ogiri ọgba ẹwọn naa, to fi mọ ile awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn ọhun to wa niluu naa.
“Lẹyin ti a ko awọn ẹlẹwọn kuro ninu ọgba ẹwọn ọhun pẹlu iranlọwọ ileeṣẹ agbofinro mii, a ṣawari pe a ko ri ẹlẹwọn 281.”
Abubakar fi kun pe ileeṣẹ ọhun ni gbogbo iroyin nipa awọn ẹlẹwọn naa lọwọ, eyii to fi lede ninu atẹjade naa.
O ni “a n ṣiṣẹ pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ẹka gbofinro mii lati ṣawari wọn.
“Lọwọ yii, ẹlẹwọn mẹtadinlogun ni a ti mu, ti a si ti da pada sinu ọgba ẹwọn, iṣẹ ṣi n lọ lọwọ lati ṣawari awọn to ku ki a le da wọn pada.”
Lẹyin naa lo fi da awọn araalu loju pe iṣẹlẹ naa ko ni ṣe akoba kankan fun abo araalu.
