EFCC pe Afọbajẹ Ọ̀yọ́ méje lórí ẹ̀sùn gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fúnpò Alaafin tuntun

EFCC pe Afọbajẹ Ọ̀yọ́ méje lórí ẹ̀sùn gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fúnpò Alaafin tuntun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀kánjúà ń dàgbà ọgbọ́n inú ẹ̀ ń rewájú.
Àjọ tó ń gbógun ti ìwà àjẹbánu lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, EFCC sọ pé lóòótọ́ làwọn pe àwọn afọbajẹ Ìlú Ọ̀yọ́ kan láti wá dáhùn ìbéèrè nípa ẹsùn tí èèyàn kan fi kàn wọ́n.

Ẹsùn yí gẹ́gẹ́ bí EFCC ṣe sọ ní í ṣe pẹ̀lú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti yan Aláàfin Ọ̀yọ́ tuntun nínú àwọn tó díje dupò náà.

Agbẹnusọ àjọ náà Dele Oyewale ló fìdí ọ̀rọ̀ yí múlẹ̀ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwoò pẹ̀lú akọ̀ròyìn

Ó ní ọ́fìsì àwọn tó wà ní Ìbàdàn ló fi ìwé pe àwọn kan nínú àwọn afọbajẹ Ìlú Ọ̀yọ́ láti wá dáhùn ìbéèrè ẹ̀sùn àjẹbánu tí olùpẹ̀jọ́ kan fi kàn wọ́n.

”Àwọn méje la fi ìwé pè, méjì nínú wọn sì dáhùn ìpè wa tí wọ́n sì ti wí tẹnu wọn”

Dele Oyewale sọ pé àjọ ọ̀hún kò lè dárúkọ àwọn tó fi ẹsùn kan àwọn afọbajẹ yìí.

Bẹ́ẹ̀ ló sì ní àwọn kò tún lè dárúkọ àwọn tí àwọn fìwé pé nínú àwọn afọbajẹ náà.

”Kò sí nínú ìlànà wa láti dárúkọ wọn. A kò sì tún lè sọ olùdíje tí wọ́n fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n gba owó lọ́wọ́ rẹ”

Ọjọ́ kẹtàlélógún, osù kẹrin, ọdún 2022 ni Ọba Atanda Olayiwola Adeyemi wàjà.

Ó lo ọdún méjìléláàdọ́ta lórí àléfà kó tó wàjà.

Láti ìgbà tó ti papòdà ni àwọn tó ń díje dupò náà ti ń kópa nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lọ́dọ̀ àwọn Ọ̀yọ́ Mèsì tó ń ṣètò ẹni tí yóó di Aláàfin tuntun.
Mọ́kàndínláàdọ́rù-ún làwọn tó ń du ipò yí.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *