
Ẹ má dá láṣà àti dáná ogun láàrin Ifẹ̀ , Mọdákẹ́kẹ́” Àwọn ẹ̀gbẹ́ kan
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn aṣáájú ìlú Iléefẹ̀ àti Mọdákẹ́kẹ́, níìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ti sọ pé kò ní í sí ààyè fún ogun abẹ́lé láàrin ìlú méjèèjì mọ́, dípò bẹ́ẹ̀, ìtùbí-nnùbí làwọn yoo fi máa yanjú aáwọ̀ tó bá fẹ́ẹ́ ṣẹlẹ̀.
Níbi ìpàdé oníròyìn kan ni Ààrẹ ẹgbẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní Great Ife Movement, Ọ̀gbẹ́ni Fẹmi Oyeyinka, ti sọ pé púpọ̀ nǹkan làwọn èèyàn ìlú Mọdakẹkẹ ń ṣe báyìí tó tún lè dá wàhálà sílẹ̀ láàrin ìlú méjèèjì.
Lára àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn èèyàn ọhún ni bí wọ́n ṣe ń fi baálẹ̀ jẹ láwọn agbègbè Ifẹ̀, bí wọ́n ṣe ń gbé pátákó ajúwe tí wọ́n kọ orúkọ Mọdákẹ́kẹ́ sí sórí ilẹ̀ tó jẹ́ ti Ifẹ̀, kíkùnà láti san ìṣákọ́lè láwọn oko (farm) tó jẹ́ tí Ifẹ̀.
Oyeyinka ṣàlàyé pé pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwọn kò fẹ́ wàhálà rárá, ìdí nìyí táwọn fi ń ké sí àwọn arógunyọ̀ láàrin ìlú méjèèjì láti mọ̀ pé ìbẹ̀rẹ̀ ogun làá rí, kò sẹ́ni tó ń rí òpin rẹ̀.
Ó ké sí àwọn aṣáájú ìlú Mọdákẹ́kẹ́ láti bá àwọn èèyàn wọn sọ̀rọ̀, kí wọ́n ṣe ohun tó tọ́, tí yóò sì mú àlàáfíà wà láàrin ìlú méjèèjì.
Ó ní ìrírí ti fi hàn pé bí ogun bá wáyé fún ogún ọdún, ìfikùnlukùn náà ni yóò padà yanjú ẹ, gbogbo ẹ̀mí tó ti lọ kò ní í ṣeé dá padà, àwọn nǹkan ìní tó sì ṣòfò kò ní í ṣeé rí padà.
Nínú ọrọ̀ tirẹ, Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ìlú Mọdákẹ́kẹ́, Ọ̀jọ̀gbọ́ọ Peter Ọlawuni, ṣàlàyé pé iyalẹnu ló jẹ́ fún òun pé àwọn èèyàn Ifẹ̀ tún lè máa ka ẹ̀sùn sí Mọdákẹ́kẹ́ lẹsẹ.
Ó ní láìpẹ́ yìí ni Ògúnṣuà ìlú Mọdákẹ́kẹ́, Ọba Joseph Toriọla, ṣì lọ sí ààfin Ọọ̀ni Ifẹ, Ọba Adéyẹyè Ẹnitan Ògúnwùsì, tó sì fún un ní ọ̀wọ̀ àti ọlá tó tọ sí i.
Ọlawuni ṣàlàyé pé àwọn agbẹjọ́rò ìlú méjèèjì tún ṣèpàdé láìpẹ́ yìí láti jíròrò lórí bí ìjókòó yóò ṣe wà láti sọ̀rọ̀ lórí aáwọ̀ kọ̀ọ̀kan tó ń yọjú láàrin ìlú méjèèjì.
Ó ṣàlàyé pé ìlú méjèèjì ti n gbé pap láti nnkan bíi ọgọ́rùn-ún ọdún ṣẹ́yìn, ṣe ni wọ́n gbọdọ̀ gbà láti gbé papọ̀ pẹ̀lú àlààfíà, nítorí ogun kìí bímọ tó dára.
Oloun Koni jaa ri ogun, Alaafia Lo dara, ti osi je oun gbogi ti irepo Lee fi wa Lari awa enia.
Imoran temi niwipe ko awon Ilu mejeeji fi owo sowopo, ki won si mo gba esu laye laari won. Oloun koni je ari ogun oo. (Aamin) .
Bakana mose daansaaki ogaami( Mr Femi Akinsola) Eku ise takun takun .