
Davido gbé fọ́nrán tuntun fún orin ‘Jayé Lọ’ jáde láìsí awuyewuye láti ọ̀dọ̀ àwùjọ Mùsùlùmí
Mary Fágbohùn
Gbajumo olorin takasufe, Davido ti gbe eya fonran orin tuntun to je ti eni to wa labe ile ise orin re, Logos Olori ti o pe akole re ni ‘Jaye Lo’ jade.
Fonran tuntun naa jade leyin ose die ti Davido yo fonran akoko kuro lori ghigno oju opo ayelujara, leyin opolopo idalebi lori iran ti o jo mo esin ninu orin naa.
Irohin jade pe Davido ni osu keje ri idoju ija ko lati odo awujo Musulumi ti won ri iran kan ninu fonran orin ‘Jaye lo’ bi nnkan iwosi.
Nigba to fi fonran tuntun lede ni ojo Eti, ti ajo onirohin kan si ye e wo, won ri pe iran ti o fa awuyewuye naa ni won ti yo kuro ninu fonran naa.
O fi oro ifori sori fonran naa, Davido ko o pe: “Ojulowo fonran fun @logosolori Jaye Lo ti jade bayii. 30BG e je ki a lo. Fonran yi kun fun idaraya pupo. Olori Gbemidebe 2.0 MUU SISE.”