Àwọn ológun kéde bíbọ́ sórí àlèéfà ìjọba ní Gabon

Àwọn ológun kéde bíbọ́ sórí àlèéfà ìjọba ní Gabon

Fẹ́mi Akínṣọla

Ń ṣe ni ọ̀rọ̀ ìdìtẹ̀gbàjọba láwọn ìlú kan nílẹ̀ Adúláwọ̀ wá n fojoojúmọ́ ràn mọ̀ ọ̀ bí iná pápá báyìí ni bí àwọn ọmọ ogun ní Gabon tí bọ sórí ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán pé àwọn ti gbàjọba orílẹ̀ èdè náà.

Wọ́n ní àwọn wọ́gilé èsì ìdìbò tó wáyé ní orílẹ̀ èdè náà lópin ọ̀sẹ̀ níbi tí wọ́n ti kéde Ààrẹ orílẹ̀ èdè ọ̀hún Ali Bongo pé òun ló jáwé olúborí.

Àjọ elétò ìdìbò orílẹ̀ èdè Gabon ní Bongo ló jáwé olúborí nínú ó dín díẹ̀ nínú ìdá méjì gbogbo ìdìbò tí wọ́n dì níbi ètò ìdìbò náà.

Ìdìtẹ̀gbàjọba yìí ni yóò fi òpin sí ọdún mẹ́tàléláàdọ́ta tí ẹbí Ali Bongo ti ń jẹ Ààrẹ Gabon.

Àwọn ọmọ ogún bíi méjìlá ló kó ara wọn jọ sórí amóhùnmáwòrán lọ́jọ́rú láti kéde pé àwọn ti wọ́gilé èsì ìdìbò náà àti pé gbogbo àwọn iléeṣẹ́ tó jẹ́ ti orílẹ̀ èdè náà ni àwọn ti fòfin dè.

Bákan náà ni wọ́n sọ wí pé gbogbo ẹnubodè tó wọ orílẹ̀ èdè ọ̀hún ni àwọn ti tì pa títí di ìgbà kan ná.

Tí ìdìtẹ̀gbàjọba yìí bá filè kẹ́sẹ járí, òhun ló máa jẹ́ ìdìtẹ̀gbàjọba kẹjọ tí yóò wáyé nílẹ̀ Adúláwọ̀ ní àwọn orílẹ̀ èdè tí ìjọba ilẹ̀ Faransé kó lẹ́rú.

Àwọn ológun náà ní àwọn wà lára ìgbìmọ̀ kan tó wà fún àtúntò orílẹ̀ èdè náà àti pé àwọn jẹ́ aṣojú àwọn ọmọ ogún orílẹ̀ èdè náà.

Ọ̀kan nínú àwọn ológun náà ní àwọn dìde láti dá ààbò bo àláfíà orílẹ̀ èdè Gabon nípa fífi òpin sí ìṣèjọba tó wà lóde èyí tó ti ń wakọ̀ orílẹ̀ èdè náà lọ sí oko ìparun.

Lẹ́yìn ìkéde yìí ni ìró ìbọn ń dún lákọlákọ ní olú ìlú orílẹ̀ èdè náà, Libreville.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *