Àwọn afọbajẹ Ìsẹ́yìn kéde Sefiu Oyebola gẹ́gẹ́ bíi Asẹ́yìn tuntun
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn afọbajẹ ìlú Ìsẹ́yìn ti kéde ọba titun fún ipò Asẹ́yìn ti ìlú Ìsẹ́yìn.
Ọmọọba Ṣẹfiu Oyebọla ni wọ́n kéde gẹ́gẹ́ bí Asẹ́yìn tuntun.
Àwọn afọbajẹ ìlú Ìsẹ́yìn kéde Oyebọla gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóó bọ́ sípò ọba ìlú Ìsẹ́yìn ní ààfin asẹ́yìn lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ṣe sọ, àwọn afọbajẹ mẹ́wàá ló dìbò yan Ọmọọba Oyebọla sórí àpèrè Ọba ìlú náà.
Ẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́ta ní Ọmọọba Ṣẹfiu Oyebọla.
Àwọn ọmọọba méjìlá ló jáde du ipò asẹ́yìn lẹ́yìn tí Asẹ́yìn àná, Ọba Ganiyy Adekunle Ajínasẹ̀ .
Ó ti pé ọdún kan báyìí ti Asẹ́yìn Adekunle Ajínasẹ̀ wàjà ní ilé ìwòsàn ńlá UCH nílùú Ìbàdàn.
Ọdún márùndínlógún ló sì lò lórí oyè kò tó wọ káà ilẹ̀ sùn.
Níbáyìí, ohun tó kàn ni fún àwọn afọbajẹ láti fi orúkọ Asẹ́yìn tuntun tí wọ́n yan náà ṣọwọ́ sí Gómìnà Sèyí Mákindé àti ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fún ìgbàwọlé àti láti gba ọ̀pá àṣẹ.
