Àwo̩n ò̩jè̩ wé̩wé̩ olórin kò nílò láti dámi mò̩ bíi ako̩ni – 2baba Idibia
Mary Fágbohùn
Ogbontarigi olorin Naijiria, Innocent Ujah Idibia, ti a mo si 2Baba, ti so pe iran awon olorin tuntun ko o nilo lati da oun mo bii akoni.
O ni oun moriri igba ti won ba kan saara idanimo si oun bii akoni, sugbon ko pon dandan ki won se bee.
Olorin African Queen naa so eyi nigba to farahan lori eto Afrobeats podcast ti Adesope Olajide, ti a mo si Shopsydoo se atokun re.
O wi pe, “Ko si eni to je mi nnkan. Fun mi, o [ipo akoni mi] wa nibe. Ko le e kuro rara. Ko din eni ti mo je ku bi oje wewe olorin kan o ba da ipo akoni mi mo.
“Nnkan eyokan ni pe, loooto, mo moriri re nigba ti awon eniyan da mo [ipo akoni mi]. Ko si eni ti ko ni moriri re. Emi naa moriri re ki awon eniyan da a mo sugbon mi o fi se nnkan ibinu ti won o ba se bee. Ohun ti eni naa ko mo niyen.
“Ko si eni to je mi ni nnkankan nitori pe gbogbo eniyan to wa, ni won yoo so itan ti won. Mo ni so itan temi. Gbogbo olorin to ba dide bayii, koda ti won ba ri imisi lati odo mi tabi elomiran, won yoo soro lati gbe ara won ga. Itan ti won niyen.
