Otolorin

Àwo̩n olórin Naijiria mú kí àwo̩n olórin Ghana dà bíi ìgò omi – Shatta Wale

Àwo̩n olórin Naijiria mú kí àwo̩n olórin Ghana dà bíi ìgò omi – Shatta Wale

Olorin ile ijo ti Ghana, Charles Nii Armah Mensah Jr., ti a mo si Shatta Wale, ti so pe aseyori awon olorin Naijiria mu ki aseyori awon elegbe won ni Ghana da bii ti emi ti ko rowo yo.

O so pe ile ise orin Ghana da bii “igo omi” legbe ile ise orin Naijiria, eyi ti o sapejuwe bii “igo oti Hennessy”.

Shatta Wale so eyi nigba to n ki olorin Naijiria to sese n dide bo, Asake, eni to sese ta gbogbo tiketi iwole si gbagede to le gba oke kan eniyan ni O2 Arena ni London, United Kingdom ku oriire.

Ni oju opo Twitter re, o ko o pe; “Awon Naijiria [olorin] n mu ki orin Ghana da bii igo omi legbe igo oti Hennessy. Mo ki Asake ku oriire!!!

“E n sare pupo jo …O ga o
“PS: Awon okunrin Ghana beere pe bawo na se se e?

“Emi: nigba ti o ba ti dekun lati maa da awon eniyan to wa nibi lejo bii pe Angeli ni o, mo ro pe a le ri eto naa.

“Naijiria n bori NI IGBA NLA !!! Eyin eniyan mi.”

Ìsèjọba tí kò dára ló fàá tí àwọn ọmọ wa se ń JA PA – Charly Boy

Ìsèjọba tí kò dára ló fàá tí àwọn ọmọ wa se ń JA PA – Charly Boy

Mary Fagbohun

Olorin, Charles Oputa, ti a mo si Charly Boy, ti so pe awon eniyan n kuro ni Naijiria lo si ile okeere nitori isejoba ti ko dara ni orile ede yi.

Irohin jade pe Naijiria n dojuko orisirisi nnkan to n se okunfa idinkun opolo pipe ni orile ede yi nitori bi ogooro awon ojogbon se n ko lo si ile Europe ati Ariwa Amerika ni ona lati wa ibi ti ile ti deju.

Nigba to fi fonran ogunlogo odomode olubewe to peju si gbagede ti a ti n bewe fun iwe irinna lo si Uk (UK Visa Application Centre, TSL) ni Ikeja, Eko, lede laipe yi, Charly Boy kedun bi ogooro olopolo pipe se n fi orile ede yi sile.

O fi oro ifori sori fonran naa pe, “Gbagede ti a ti n gba iwe irinna lo si UK (UK Visa Application Centre, TSL) Ikeja ni Eko lana.

“Awon ojogbon wa to dara ju n fi ipago ti a ko yi sile.

“Bi a se fi aaye gba eyi to buru ju lara wa lati dari eyi to dara ju lara wa.”

Ẹ mójútó ṣẹ́ ni o, ọmọ Nàìjíríà ò fẹ́ gbọ́ àwáwí. Tinubu pàrọwà sáwọn Mínísítà

Ẹ mójútó ṣẹ́ ni o, ọmọ Nàìjíríà ò fẹ́ gbọ́ àwáwí. Tinubu pàrọwà sáwọn Mínísítà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà ní ìrètí pipẹ àárẹ̀ tó gbópọn ní-ín dá sínú ọkàn onírètí.
“Èmi ni awakọ̀, gbogbo àwọn ọmọ Naijiria ni wọn jókòó sí ẹ̀yìn mi ti wọ́n si n wòye bí èmi àti yín ṣe n tukọ̀ yii.Àwọn sì ni èrò ọkọ̀ yìí”

Ọ̀rọ̀ tí Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Bọla Ahmed Tinubu sọ fún àwọn Mínísítà tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ búra fún gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìgbìmọ̀ ìṣèjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ààrẹ Tinubu ní gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ń retí ìgbésẹ akin èyí tí yóó mú ìrètí ọ̀tun tí ìṣèjọba òun dúró lé lórí jáde.

Ó ní gbogbo àwọn Mínísítà yìí ló ní ipa láti kó lọ́nà àti rí pé gbogbo ìlérí wọ̀nyí bọ́ síi fún wọn.

Ó ní gbogbo àwọn Mínísítà náà gbọdọ̀ mọ̀ pé àwọn kìí ṣe Mínísítà agbègbè kóówá wọn tàbí ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti wá bíkòṣe aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lápapọ̀.

Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ṣètò ìbúra fún àwọn Mínísítà tuntun fún ìgbìmọ̀ ìṣàkóso ìjọba àpapọ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn lọ́jọ́ Ajé.

Àwọn Mínísítà marundinlaadọta ní Aàrẹ búra fún ní gbọ̀ngán ìgbàlejò nlá tó wà ní ilé Ààrẹ ní Aso Rock Villa nílùú Abuja.

Àwọn Mínísítà tí wọ́n búra fún lọjọ Ajé rèé:

Mínísítà fún ọ̀rọ̀ abẹ́lé, Bunmi Tunji-Ojo
Mínísítà fún ibanisọrọ, ọgbọn inu ati ọrọ̀ ajé ìgbàlódé, Bosun Tijani
Mínísítà fún ètò ìṣúná àti ọrọ̀ ajé, Wale Edun
Mínísítà fún ọrọ ajé inú omi, , Adegboyega Oyetola
Mínísítà fún ohun àmúṣagbára, Adedayo Adelabu
Mínísítà Kejì fún ètò ìlera àti ìgbáyégbádùn aráàlú Tunisia Alausa
Mínísítà fún ìdàgbàsókè òhun àlùmọ́nì ilẹ̀, Dele Alake
Mínísítà fún ìrìnàjò afẹ́, Lola Ade-John
Mínísítà fún ìdálẹ́ṣẹsílẹ̀, kátàkárà àti ìdókoòwò, Doris Anite
Mínísítà fún ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ, Uche Nnaji
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́ àti ìgbanisíṣẹ́, Nkiruka Onyejeocha
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin, Uju Kennedy
Mínísítà fún iṣẹ́ òde, David Umahi
Mínísítà fún ìdàgbàsókè ẹkùn Niger Delta, Abubakar Momoh
Mínísítà fún ètò ìgbógun ti ìṣẹ́, Betta Edu
Mínísítà fún ìdàgbàsókè afẹ́fẹ́ gáàsì, Ekperikpe Ekpo
Mínísítà fún epo rọ̀bì, Heineken Lokpobiri
Mínísítà fún ìrìnnà òfurufú Festus Keyamo
Mínísítà fún eré ìdárayá, John Enoh
Mínísítà fún olú ìlú Nàìjíríà, Nyesom Wike
Mínísítà fún àṣà, ìṣe àti ọ̀rọ̀ ajé ẹbùn ọpọlọ, Hannatu Musawa
Mínísítà ètò àbò, Mohammed Badaru
Mínísítà Kejì fún ètò àbò, Bello Matawalle
Mínísítà kejì fún ètò ẹ̀kọ́, Yusuf T. Sunumu
Mínísítà fún iléègbé àti ìdàgbàsókè ìlú, Ahmed M. Dangiwa
Mínísítà kejì iléègbé àti ìdàgbàsókè ìlú, Abdullah T. Gwarzo
Mínísítà fún àtò ọrọ̀ ajé, Atiku Bagudu
Mínísítà kejì fún olú ìlú Nàìjíríà, Mairiga Mahmud
Mínísítà kejì fún ìpèsè omi àti ìmọ́tótó àyíká, Bello M. Goronyo
Mínísítà fétò Ọ̀gbìn àti ìpèsè oúnjẹ, Abubakar Kyar
Mínísítà fétò ẹ̀kọ́, Tahir Maman
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè, Yusuf M. Tuggar
Mínísítà fún ètò ìlera, Ali Pate
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́pàá, Ibrahim Geidam
Mínísítà kejì fún ìdàgbàsókè irin tútù, U. Maigari Ahmadu
Mínísítà fún ìdàgbàsókè irin tútù, Shuaibu A. Audu
Mínísítà fún ètò ìròyìn, Muhammed Idris
Agbẹjọ́rò àgbà àti Mínísítà fún ètò ìdájọ́, Lateef Fagbemi
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́ àti ìgbanisíṣẹ́, Simon B. Lalong
Mínísítà kejì fún àwọn ọlọ́pàá, Imaan Sulaiman-Ibrahim
Mínísítà fún àkànṣe iṣẹ́ àti ajọṣepọ àwọn ẹ̀ka ìjọba, Zephaniah Jisalo
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ omi àti ìmọ́tótó àyíká, Joseph Utsev
Mínísítà kejì fún ètò ọ̀gbin àti ìpèsè oúnjẹ, Aliyu Sabi Abdullahi

llé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó kọ̀ láti fi òǹtẹẹ̀ lu àwọn orúkọ kan fún ipò Kọmísọ́nà

llé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó kọ̀ láti fi òǹtẹẹ̀ lu àwọn orúkọ kan fún ipò Kọmísọ́nà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó lọ́jọ́rú kọ̀ jálẹ̀ láti fòntẹ̀ lu ìyànsípò àwọn Kọmísọ́nà tẹ́lẹ̀ tí Gómìnà Babajide Sanwo-Olu fàkalẹ̀ fún àyẹ̀wò.

Àwọn Kọmísọ́nà tẹ́lẹ̀ náà ni Gbenga Omotoso, Akin Abayomi àti Sam Egube.

Àwọn yòókù ni Cecila Dada, Olalere Odusote àti Folashade Adefisayo.

Orúkọ àwọn wọ̀nyí ló wà lára orúkọ Kọmísọ́nà tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó dápadà fún Gómìnà.

Orúkọ àwọn wọ̀nyí ló wà lára orúkọ Kọmísọ́nà tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó dápadà fún Gómìnà.

Èyí ló wà nínú àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó, Bisola Branco Adekola buwọ́lù fún àwọn akọ̀ròyìn.

Ìdá àádọta àwọn tí wọ́n dápadà ló ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Gómìnà Babajide Sanwo-Olu ní sáà tó lọ.

Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó, Rt Hon Mudashiru Obasa ni ìgbésẹ̀ ilé ló dá lé lórí àyẹ̀wò tí ẹ̀ka ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin tó ń rísí àyẹ̀wò síse tí Akójàánu ilé, Fatia Mojeeb léwájú rẹ̀.

Abẹnugan ilé wá kan sáárá sí ẹ̀ka fún isẹ́ takuntakun, tó sí tún rọ àwọn Kọmísọ́nà ti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin buwọ́lù láti rí i dájú pé àwọn sin aráàlú ní ìlànà tó bá òfin mu.

Olórin Simi sàfihàn èròńgbà rẹ̀ láti fẹ̀yìntì

Olórin Simi sàfihàn èròńgbà rẹ̀ láti fẹ̀yìntì

Mary Fágbohùn

Gbajugbaja olorin-akorin sile Simisola Kosoko, ti a n pe ni Simi, ti safihan erongba re lati feyinti.

Eni odun marundinlogoji naa so pe oun yoo bere eto omode to je ti oun leyin ti oun ba fi ise orin sile.

O so eyi di mimo lati oju opo Twitter re ni ojo Abameta.

Iya omo kan naa so pe oun ti sise lori orin fun opolopo odun.

Simi ko o pe, “Erongba ifeyinti mi lati se eto omode to je temi. Mo ti sise lori orin fun opolopo odun. Mi o le e duro. Ki Olorun ran mi lowo .”

Ẹ má dá láṣà àti dáná ogun láàrin Ifẹ̀ , Mọdákẹ́kẹ́” Àwọn ẹ̀gbẹ́ kan

Ẹ má dá láṣà àti dáná ogun láàrin Ifẹ̀ , Mọdákẹ́kẹ́” Àwọn ẹ̀gbẹ́ kan

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn aṣáájú ìlú Iléefẹ̀ àti Mọdákẹ́kẹ́, níìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ti sọ pé kò ní í sí ààyè fún ogun abẹ́lé láàrin ìlú méjèèjì mọ́, dípò bẹ́ẹ̀, ìtùbí-nnùbí làwọn yoo fi máa yanjú aáwọ̀ tó bá fẹ́ẹ́ ṣẹlẹ̀.

Níbi ìpàdé oníròyìn kan ni Ààrẹ ẹgbẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní Great Ife Movement, Ọ̀gbẹ́ni Fẹmi Oyeyinka, ti sọ pé púpọ̀ nǹkan làwọn èèyàn ìlú Mọdakẹkẹ ń ṣe báyìí tó tún lè dá wàhálà sílẹ̀ láàrin ìlú méjèèjì.

Lára àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn èèyàn ọhún ni bí wọ́n ṣe ń fi baálẹ̀ jẹ láwọn agbègbè Ifẹ̀, bí wọ́n ṣe ń gbé pátákó ajúwe tí wọ́n kọ orúkọ Mọdákẹ́kẹ́ sí sórí ilẹ̀ tó jẹ́ ti Ifẹ̀, kíkùnà láti san ìṣákọ́lè láwọn oko (farm) tó jẹ́ tí Ifẹ̀.

Oyeyinka ṣàlàyé pé pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwọn kò fẹ́ wàhálà rárá, ìdí nìyí táwọn fi ń ké sí àwọn arógunyọ̀ láàrin ìlú méjèèjì láti mọ̀ pé ìbẹ̀rẹ̀ ogun làá rí, kò sẹ́ni tó ń rí òpin rẹ̀.

Ó ké sí àwọn aṣáájú ìlú Mọdákẹ́kẹ́ láti bá àwọn èèyàn wọn sọ̀rọ̀, kí wọ́n ṣe ohun tó tọ́, tí yóò sì mú àlàáfíà wà láàrin ìlú méjèèjì.

Ó ní ìrírí ti fi hàn pé bí ogun bá wáyé fún ogún ọdún, ìfikùnlukùn náà ni yóò padà yanjú ẹ, gbogbo ẹ̀mí tó ti lọ kò ní í ṣeé dá padà, àwọn nǹkan ìní tó sì ṣòfò kò ní í ṣeé rí padà.

Nínú ọrọ̀ tirẹ, Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ìlú Mọdákẹ́kẹ́, Ọ̀jọ̀gbọ́ọ Peter Ọlawuni, ṣàlàyé pé iyalẹnu ló jẹ́ fún òun pé àwọn èèyàn Ifẹ̀ tún lè máa ka ẹ̀sùn sí Mọdákẹ́kẹ́ lẹsẹ.

Ó ní láìpẹ́ yìí ni Ògúnṣuà ìlú Mọdákẹ́kẹ́, Ọba Joseph Toriọla, ṣì lọ sí ààfin Ọọ̀ni Ifẹ, Ọba Adéyẹyè Ẹnitan Ògúnwùsì, tó sì fún un ní ọ̀wọ̀ àti ọlá tó tọ sí i.

Ọlawuni ṣàlàyé pé àwọn agbẹjọ́rò ìlú méjèèjì tún ṣèpàdé láìpẹ́ yìí láti jíròrò lórí bí ìjókòó yóò ṣe wà láti sọ̀rọ̀ lórí aáwọ̀ kọ̀ọ̀kan tó ń yọjú láàrin ìlú méjèèjì.

Ó ṣàlàyé pé ìlú méjèèjì ti n gbé pap láti nnkan bíi ọgọ́rùn-ún ọdún ṣẹ́yìn, ṣe ni wọ́n gbọdọ̀ gbà láti gbé papọ̀ pẹ̀lú àlààfíà, nítorí ogun kìí bímọ tó dára.

Èèwọ̀! Ègún ayérayé ni ,kí Oníṣẹ̀ṣe kún aṣebi lọ́wọ́—- ẹgbẹ́ oníṣẹ̀ṣe

Èèwọ̀! Ègún ayérayé ni ,kí Oníṣẹ̀ṣe kún aṣebi lọ́wọ́—- ẹgbẹ́ oníṣẹ̀ṣe

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ni èèyàn tí yóó bá bani lórin jẹ́,kìí kọ ọ́ bí olórin.Bí aráalé rẹ bá lẹ́nu, jẹ́ kí ẹsẹ̀ tì ẹ náà yá
nílẹ̀ kánmọ́ kánmọ́.
Gbogbo ẹgbẹ́ oníṣẹ̀ṣe ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti rọ àwọn agbófinró àti àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti yé fi ojú ti kò tọ́ wo àwọn mọ́.

Ààrẹ Ìṣẹ̀ṣe ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Olukunmi Omikemi nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ níbi ayẹyẹ ọdún Iṣẹṣe tí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó wáyé nínú Gbongan Mapo ní Ìbàdàn ṣàlàyé pé, ọ̀pọlọpọ ìgbà ló jẹ́ pé tí nǹkan burúkú bá ti ṣẹlẹ̀ ní wọ́n máa ń rò ó sí àwọn oníṣẹ̀ṣe

Omikemi ní ti àwọn nǹkan náà bá nííṣe pẹ̀lú gígé ẹ̀yà ara ènìyàn tàbí ogun owó ni wọ́n máa ń rò pé àwọn ni àwọn wà nídìí rẹ̀.

Ó ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn èèyàn máa ń na ìka àlèébù sí àwọn lórí nǹkan tí àwọn kò ní mọwọ́ mẹsẹ̀ lé lórí, tó sì rọ àwọn ará ìlú láti máa ṣe ìwádìí ṣáájú kí wọ́n tó nàka àlèébù sí àwọn oníṣẹ̀ṣe.

Omikemi dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fún ànfààní tó fún àwọn oníṣẹ̀ṣe ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọdun yìí tó sì tún rọ Gómìnà Mákindé láti fún àwọn oníṣẹ̀ṣe ní ààyè nínú ìṣèjọba rẹ̀ kí wọ́n lè gbé Àṣà àti ẹ̀ka Ìgbafẹ́ lárugẹ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Mọ́gàjí Fáyẹmí Fákáyòdé nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe níbi ètò ọ̀hún ṣàlàyé pé Ìṣẹ̀ṣe ni orísun ohun gbogbo tó ní-ín ṣe pẹ̀lú ìran Odùduwà.

Davido gbé fọ́nrán tuntun fún orin ‘Jayé Lọ’ jáde láìsí awuyewuye láti ọ̀dọ̀ àwùjọ Mùsùlùmí

Davido gbé fọ́nrán tuntun fún orin ‘Jayé Lọ’ jáde láìsí awuyewuye láti ọ̀dọ̀ àwùjọ Mùsùlùmí

Mary Fágbohùn

Gbajumo olorin takasufe, Davido ti gbe eya fonran orin tuntun to je ti eni to wa labe ile ise orin re, Logos Olori ti o pe akole re ni ‘Jaye Lo’ jade.

Fonran tuntun naa jade leyin ose die ti Davido yo fonran akoko kuro lori ghigno oju opo ayelujara, leyin opolopo idalebi lori iran ti o jo mo esin ninu orin naa.

Irohin jade pe Davido ni osu keje ri idoju ija ko lati odo awujo Musulumi ti won ri iran kan ninu fonran orin ‘Jaye lo’ bi nnkan iwosi.

Nigba to fi fonran tuntun lede ni ojo Eti, ti ajo onirohin kan si ye e wo, won ri pe iran ti o fa awuyewuye naa ni won ti yo kuro ninu fonran naa.

O fi oro ifori sori fonran naa, Davido ko o pe: “Ojulowo fonran fun @logosolori Jaye Lo ti jade bayii. 30BG e je ki a lo. Fonran yi kun fun idaraya pupo. Olori Gbemidebe 2.0 MUU SISE.”

Ìdí tí mo fi lọ sí ibi ètò ‘America’s Got Talent’ – Josh2funny

Ìdí tí mo fi lọ sí ibi ètò ‘America’s Got Talent’ – Josh2funny

Mary Fágbohùn

Gbajumo aderin-in-posonu Naijiria, Josh Alfred, ti a mo si Josh2Funny, ti safihan pe  kikopa oun lori eto mohunmaworan ni, Amerika ni ebun (America’s Got Talent), kii se lati dije fun ebun sugbon lati safihan ebun ti oun ni.

E ranti pe Josh2Funny eni ti a mo fun fonran alawada idanwo afenuka ti o n se, gbe ebun re lo lati sere ni itage ti o tobi ju lagbaye, Amerika ni ebun (America’s Got Talent), laipe yi.

Gege bi o se so, awon asagbekale eto naa fi iwe pe e wa sibe lati mu ki awon oluworan rerin arin takiti.

Onifonran naa so eyi ninu iforo-wani-lenu-wo kan to se pelu iwe irohin Punch.

O wi pe, “Won pe mi wa si ori eto naa lati se nnkan ti mo se. Mo lo sibe lati lo safihan ‘Josh2funny’, eyi to je ohun ti awada mi da le lori.”

Aderin-in-posonu eni odun mejilelogbon naa mu ki awon oluworan rerin arin gbokiti pelu ere meta ti o se bii eni to yara ka iwe ju, eni to le yara soro orin ni kiakia ju ati pidanpidan lori eto naa.

Bo ti le je pe awon kan lara awon adajo lori eto naa ni ere alawada re daru mo oun loju ti won si fun ni “rara” ni igba meteeta, Simon fun Josh ni “bee ni” ninu igbiyanju re to se keyin, ti o si gboriyin fun imose awada re.

Agbára Sunday Igboho kò jóná m’ọ́lé

Gbogbo igbiyanju Oloye Sunday Adeyemo ti gbogbo eniyan mo si Sunday Igboho lati gba eya Yoruba lowo awon darandaran ni awon olote kan tun fe fi ibi su.

Sunday Igboho lo gba awon omo Yoruba sile ni ojo Eti to koja nigba ti o lo dun ikooko mo olori awon Fulani naa. Gege bi o se salaye, o ni gbogbo ibon ti won yin si oun lo domi. Owo lo fi n gba ibon owo awon omo Fulani naa.

Eyi tun fe fa ede aiyede laarin Gomina Ipinle Oyo, Ogbeni Seyi Makinde pelu Sunday igboho pelu komisona olopaa ipinle naa titi de odo Inspector General ti se oga olopaa patapata. Gomina Makinde lo fogbon too ki ilu ma ba daru mo lori nitori awon odo kan tun duro pe ti ijoba ba dan an wo pere ti won fi owo sinkun ofin mu u, awon ko ni je ki isinmi de ba gbogbo agbegbe naa.

Afemoju oni ojo kerindinlogbon, osu kin-in-ni odun yii ni awon kan lo dana sun ile re ni ireti pe awon ti sun gbogbo agbara to ni amo Sunday Igboho si n fi ye awon oniroyin pe agbara Yoruba ko le jona ati pe asiko oro ko tii ya nitori pe iwadii si n lo lowo lori isele naa.