Akérédolú bẹ̀rẹ̀ ìsìnmi, Aiyedatiwa yóò di adelé gómìnà l’Óndó

Akérédolú bẹ̀rẹ̀ ìsìnmi, Aiyedatiwa yóò di adelé gómìnà l’Óndó

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìgbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, Lucky Aiyedatiwa, ni yóò di adelé Gómìnà ní ìpínlẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ láti Ọjọ́rú ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, odún 2023.

Akọ̀wé Gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Richard Olatunde, ló fi eléyìí léde nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sójú òpó ìbáraẹnidọ́rẹ̀ẹ́ facebook.

Olatunde wí pé Gómìnà Akérédolú ń lọ fún ìsinmi lati lọ̀ọ́ tọ́jú ara rẹ̀, léyìí tí yóó mú kí igbákejì rẹ̀ ó delé fún un.

Àtàjẹ́de ọ̀hún sọ pé “Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, Arákùnrin Oluwarotimi Akérédolú, SAN, CON, yoo bẹ̀rẹ̀ ìsinmi tó níí ṣe pẹ̀lú ètò ìlera ní Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, ọdún 2023, láti tẹ̀síwájú nípa ìtọ́jú ara rẹ̀.

“Lákòókò ìsinmi yìí, Gómìnà Akérédolú yóò bójú tó ìlera rẹ̀ láti ríi pé òun ní àlàáfíà pípé kó tóó padà sẹ́nu iṣẹ́.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *