Èèwọ̀! Ègún ayérayé ni ,kí Oníṣẹ̀ṣe kún aṣebi lọ́wọ́—- ẹgbẹ́ oníṣẹ̀ṣe

Èèwọ̀! Ègún ayérayé ni ,kí Oníṣẹ̀ṣe kún aṣebi lọ́wọ́—- ẹgbẹ́ oníṣẹ̀ṣe

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ni èèyàn tí yóó bá bani lórin jẹ́,kìí kọ ọ́ bí olórin.Bí aráalé rẹ bá lẹ́nu, jẹ́ kí ẹsẹ̀ tì ẹ náà yá
nílẹ̀ kánmọ́ kánmọ́.
Gbogbo ẹgbẹ́ oníṣẹ̀ṣe ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti rọ àwọn agbófinró àti àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti yé fi ojú ti kò tọ́ wo àwọn mọ́.

Ààrẹ Ìṣẹ̀ṣe ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Olukunmi Omikemi nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ níbi ayẹyẹ ọdún Iṣẹṣe tí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó wáyé nínú Gbongan Mapo ní Ìbàdàn ṣàlàyé pé, ọ̀pọlọpọ ìgbà ló jẹ́ pé tí nǹkan burúkú bá ti ṣẹlẹ̀ ní wọ́n máa ń rò ó sí àwọn oníṣẹ̀ṣe

Omikemi ní ti àwọn nǹkan náà bá nííṣe pẹ̀lú gígé ẹ̀yà ara ènìyàn tàbí ogun owó ni wọ́n máa ń rò pé àwọn ni àwọn wà nídìí rẹ̀.

Ó ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn èèyàn máa ń na ìka àlèébù sí àwọn lórí nǹkan tí àwọn kò ní mọwọ́ mẹsẹ̀ lé lórí, tó sì rọ àwọn ará ìlú láti máa ṣe ìwádìí ṣáájú kí wọ́n tó nàka àlèébù sí àwọn oníṣẹ̀ṣe.

Omikemi dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fún ànfààní tó fún àwọn oníṣẹ̀ṣe ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọdun yìí tó sì tún rọ Gómìnà Mákindé láti fún àwọn oníṣẹ̀ṣe ní ààyè nínú ìṣèjọba rẹ̀ kí wọ́n lè gbé Àṣà àti ẹ̀ka Ìgbafẹ́ lárugẹ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Mọ́gàjí Fáyẹmí Fákáyòdé nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe níbi ètò ọ̀hún ṣàlàyé pé Ìṣẹ̀ṣe ni orísun ohun gbogbo tó ní-ín ṣe pẹ̀lú ìran Odùduwà.

1 thought on “Èèwọ̀! Ègún ayérayé ni ,kí Oníṣẹ̀ṣe kún aṣebi lọ́wọ́—- ẹgbẹ́ oníṣẹ̀ṣe”

  1. Solahudeen Abdullahi

    Ki oloun ko saanu awa eniyan Lori oro eke , Oro ti aani imo kikun lori re ti ama nso.
    Nisoki, dansaki fun Oluko Agba Femi Akinsola fun aafani tiko legbe yii.
    Oloun yoo bani lore emii yin lori daada Aamin)

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *