Gbogbo igbiyanju Oloye Sunday Adeyemo ti gbogbo eniyan mo si Sunday Igboho lati gba eya Yoruba lowo awon darandaran ni awon olote kan tun fe fi ibi su.
Sunday Igboho lo gba awon omo Yoruba sile ni ojo Eti to koja nigba ti o lo dun ikooko mo olori awon Fulani naa. Gege bi o se salaye, o ni gbogbo ibon ti won yin si oun lo domi. Owo lo fi n gba ibon owo awon omo Fulani naa.
Eyi tun fe fa ede aiyede laarin Gomina Ipinle Oyo, Ogbeni Seyi Makinde pelu Sunday igboho pelu komisona olopaa ipinle naa titi de odo Inspector General ti se oga olopaa patapata. Gomina Makinde lo fogbon too ki ilu ma ba daru mo lori nitori awon odo kan tun duro pe ti ijoba ba dan an wo pere ti won fi owo sinkun ofin mu u, awon ko ni je ki isinmi de ba gbogbo agbegbe naa.
Afemoju oni ojo kerindinlogbon, osu kin-in-ni odun yii ni awon kan lo dana sun ile re ni ireti pe awon ti sun gbogbo agbara to ni amo Sunday Igboho si n fi ye awon oniroyin pe agbara Yoruba ko le jona ati pe asiko oro ko tii ya nitori pe iwadii si n lo lowo lori isele naa.