Fẹ́mi Akínṣọlá
Ò̩wó̩n epo! Àwọn ọ̀dọ́ ìlú Ipokia fárígá fún ilé-iṣẹ́ aṣọ́bodè, gbèdèke ọjọ́ mẹ́rìnlá péré
Ẹgbẹ́ kan, Ipokia Local Government Youth Forum (IPYF), ti fi ẹsun kan ilé-iṣẹ́ aṣọ́bodè ilẹ̀ Nàìjíríà, Nigeria Customs Service (NSC), pé wọ́n ń gbé epo tó yẹ fún àwọn èèyàn Ipokia lọ tà ní orílẹ-èdè Benin.
Ẹgbẹ IPYF ṣọ pe eyi ko jẹ ki awọn eeyan ri epo ra ni awọn ile epo ni gbogbo ijọba ibilẹ Ipokia.
Wọn ni idaamu gidi ati owo gọbọi ni wọn fi n ra epo bẹntiroolu lọwọ awọn to n ta a lọja okunkun (Black market).
Koda, gbedeke ọsẹ meji pere ni ẹgbẹ naa sọ pe awọn fun ileeṣẹ aṣọbode Naijiria lati dẹkun bi wọn ṣe ni wọn n gbe epo to yẹ fun Ipokia lọọ ta ni ibomiran.
Wọn ni bi inira airi epo ra ti awọn n koju ba fi tẹsiwaju lẹyin ọsẹ meji, nitori bi awọn oṣiṣẹ aṣọbode ṣe n gbabọde, awọn yoo ti gbogbo ilu pa ni.
Ṣaaju ni ẹgbẹ yii ti kọkọ fi lẹta kan ṣọwọ si ọga agba ileeṣẹ aṣọbọde Naijiria, Bashir Adewale, eyi ti Alaga wọn, Imoleayo Mawutin Deji, buwọlu lorukọ ẹgbẹ.
Ninu lẹta naa ni wọn ti ṣalaye pe ọdun 2019 ni ijọba ti ṣofin awọn oniṣowo epo ko gbọdọ ta epo ni ijọba ibilẹ Ipokia.
Eyi mu ki awọn araalu o maa rin irin ogun kilomita si ilu naa, ki wọn to o ri epo ra.
Ija ti araalu ja lo mu ki ijọba pada fi aaye gba ileepo mẹrin lati maa ta epo fun wọn laarin ilu.
Ṣugbọn wọn ko ta a fun araalu, afi fun awọn ti wọn n ta a si Benin.
Gẹ́gẹ́ bí Alága ẹgbẹ́ ọdọ ìjọba ìbílẹ̀ Ipokia ṣe wí, ó ní láàrin ọsẹ méjì yíì, kawọn Aṣọbode ṣe atunyẹwo epo 20km ti wọn n ṣe fún Ipokia.
Ki wọn mojuto awọn ileepo, lati ri i pe wọn n ta a fawọn eeyan.
O ni bi wọn ko ba le ṣe eyi, ki wọn kuku ti gbogbo ile epo to wa nijọba ibilẹ Ipokia pa.
‘’Ooṣa bo o ba le gbe mi, ṣe mi bi o ṣe ba mi.
‘’Lẹyin ọsẹ meji ti a fun wọn yii, bi wọn ko ba ti da wa lohun, gbogbo ijọba ibilẹ Ipokia ati Ogun West ni awa ọdọ maa tipa.
‘’Ati oṣiṣẹ aṣọbode o, ati ọlọpaa o, a o ni i jẹ ki ohunkohun ṣiṣẹ, a maa ti i pa a ni, afi ti wọn ba da awọn eeyan wa lohun. A o si ni i yi ipinnu wa yii pada o, iya yii ti pọju.’’
Ìgbìyànjú wa láti bá àjọ Aṣọbode ilẹ̀ wa sọrọ ló já sí pàbó.
