Ara Azeez Ijaduade ti ń balẹ̀ lẹ́yìn tí ìbọn ọlọ́pàá bà á – Ẹgbẹ́ àwọn òṣèrè
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé àwọn àgbà ní àrìnfẹ́sẹ̀sí kìí ṣèrìn kan dan-in-dan-in. Adẹ́dàá nìkan ni kó máa kó wa yọ nínú ewu aye gbogbo.
Àwọn akẹgbẹ́ òṣèré tíátà Yorùbá tí ìròyìn sọ pé ọlọ́pàá yìnbọn lù ní ìpínlẹ̀ Ogun, Azeez Ijaduade ti sọ pé àlàáfíà ló wà.
Nínú fídíò kan tí ọ̀kan lára wọn, Abiodun Adebanjo, fi léde ló ti sọ̀rọ̀ náà.
Ó ní “A kàn fẹ́ kí gbogbo ayé mọ̀ ni pé Àlàáfíà ni Azeez wà, wọ́n ń tọjú rẹ̀ lọ́wọ́, ara rẹ̀ sì ti ń balẹ̀ .”
Àlàáfíà ni Azeez wà o, a kò nílò kí ẹnikẹni máa dá owó jọ fún wa lásìkò yìí.
“ Àwọn akẹgbẹ́ wa ti dé ibi tí a wà yìí, igbákejì kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ti wá sí ibí, bẹ́ẹ̀ náà ni Ààrẹ ẹgbẹ́ wa, Mr Latin náà ti yọjú síbí, a kò nílò owó kankan lásìkò yìí, kò sí ewu kankan.”
Lẹ́yìn ti Adeiofun sọ̀rọ̀ náà tán ni Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn òṣèré tíátà Yorùbá, TAMPAN, Mr Latin náà dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn aráàlú fún akitiyan wọn.
Lẹ́yìn náà ló ní kò si6 wàhálà kankan àti pé ara òṣèré ọ̀hún ti ń balẹ̀.
