Ó setán láti rúbo̩ gbogbo rè̩ fún mi’ – Tonto Dikeh banújé̩ lórí àìlera o̩po̩lo̩ Solidstar
Mary Fágbohùn
Osere tiata Naijiria, Tonto Dikeh, ti safihan ife to ni lati kan si awon alakoso tabi ebi Solidstar leyin irohin nipa pe olorin naa n ba aarun opolo finra.
E ranti pe Joseph, arakunrin Solidstar ti oruko abiso re n je Joshua Iniyezo, laipe yi lo si oju opo Instagram olorin naa lati fi fonran kan lede eyi to salaye ipo ti olorin naa wa.
O safihan pe Solidstar ti n ja pelu ailera ti ko derun lati ojo pipe, aisan yi ni idi kan gboogi to fi yago fun ise orin.
Nigba ti yoo fesi pelu itan Instagram re, Tonto Dikeh wi pe oun fe kan si awon omo egbe Solidstar.
O seranti ni olorin naa se ran an lowo nigba to n gbiyanju lati se orin ni odun die seyin.
O ko o pe, “Bawo ni mo se le kan si alakoso Solidstar tabi ebi re?
“Eje mi ni igboro niyi. O setan lati ran mi lowo ki n le se daradara nipa ti orin. Emi ni mi o kii gboran.
