Mi ò mọ̀ pé ìwà ọ̀daràn ni kí èèyàn máa jí iná ìjọba lò…Afurasì kan
Ọrẹ Òtítọ́jù
Ṣé wọ́n ní ohun téèyàn ò mọ̀ ,dájúṣáká ó ṣàgbà èèyàn.
Ọmọkùnrin ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n kan, Abdulfatai Abdulateef, ti sọ pé tó bá jẹ́ pé òun mọ̀ pé ìwà ọ̀daràn tó níjìyà lábẹ̀ òfin ni jíjí iná lò ni, òun kò ní í ṣán irú àṣọ bẹ́ẹ̀ ṣorò.
Lateef àti ẹnì kejì rẹ̀, Adeṣina Ọpẹyẹmi, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n, ni ọwọ́ àjọ sífú dìfẹ́nsì ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun tẹ̀ láìpẹ̀ yìí lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ń jí iná ìjọba lò.
Nígbà tó ń ṣàfihàn wọn fún àwọn oníròyìn nílùú Òṣogbo l’Ọjọru, ọsẹ yìí, kọmandàǹtì àjọ náà, Sunday Agboọla, ṣàlàyé pé agbègbè Akéde, ni Oke-Baalẹ, nílùú Oṣogbo, lọwọ ti tẹ awọn mejeeji.
Agboọla ṣàlàyé pé lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, lawọn mejeeji yii gbimọ-pọ lati yọ waya kuro nidii mita ile ti wọn n gbe, ti wọn si bẹrẹ si i ji ina ìjọba lo.
Ó ní eléyìí ni wọ́n ń ṣe lọwọ́ tí ọwọ́ àwọn sifu difẹnsi pẹlu iranlọwọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ amunawa IBEDC fi tẹ wọn.
Nínú àwíjàre rẹ̀, Lateef ṣàlàyé fún akọ̀ròyìn wa pe bi owo ina ti awọn ba ra ṣe tete maa n tan lo fa a ti oun ati ẹni kẹji oun fi pinnu lati yara ji ina lo lọjọ naa.
Ó ní ẹ̀rọ omi (water pumping machine) lawọn fẹẹ lo lọjọ ti ọwọ tẹ awọn, ati pe igba akọkọ ti oun yoo ṣe iru nnkan bayii ri niyẹn, oun ko si mọ pe iwa ọdaran to le gbe oun de ọdọ awọn ẹṣọ alaabo ni.
Àmọ́ ṣá, Agboọla ti sọ pe awọn ọkunrin mejeeji yoo foju bale-ẹjọ nitori iwa to n ṣakoba fun eto ọrọ-aje orileede yii ni wọn hu.
Bákan náà ló ṣàfihàn Akinloye Abiọla, ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n, lórí ẹ̀sùn dída omi àláfíà agbègbè rú.
Abiọla ni wọ́n ní ó lọ máa ń fi ìgbà gbogbo dúnkookò mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ ìwakùsà kan nílùú Iléṣà.
Agboọla ṣàlàyé pé ní kété tíwàdíì bá ti parí ni Abiọla yóò fojú balé-ẹjọ́ láti sọ ohun tó rí lọ́bẹ̀ tó fi waro ọwọ́.