Àwọn ọmọ ogun Russia dé sí ẹ̀yìnkùlé Niger, láti ṣàtìlẹ́yìn fún wọn

Àwọn ọmọ ogun Russia dé sí ẹ̀yìnkùlé Niger, láti ṣàtìlẹ́yìn fún wọn

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ọ̀rọ̀ ìdìtẹ̀-gbàjọba àti ogun tó ṣeé ṣe kó bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn ológun tó gbàjọba orílẹ-èdè Niger, àti àjọ àwọn olórí orílẹ-èdè apá Ìwọ̀òrùn ilẹ̀ Áfríkà, Economic Community of West African States (ECOWAS), ti tún bá ọnà mí-ìn yọ pẹlú bí àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Russia ṣe ti dé sórílẹ̀-èdè Mali, láti ti àwọn Niger lẹ́yìn nítorí bí wọ́n ṣe fẹ́ ẹ́ dojú ìjà kọ wọn.

Olórí àwọn ikọ ọmọ ogun tí wọ́n ń pè ní Wagner yìí, ìyẹn Yevgeny Prigozhin, tó ti kọ́kọ́ lọ sí orílẹ-èdè Congo, ni wọ́n rí ní Mali laipẹ yìí nínú fídíò kan tó fi síta. Papaapa ló dì nínú aṣọ ológun rẹ̀, àlàyé tó sì ṣe ni pe awọn ko awọn ọmọ ogun lọ si Mali lati ba awọn ologun to n dari orile-ede naa koju awọn agbesunmọmi, atawọn ogun mi-in to n doju kọ wọn ni.

Ṣáájú àkókò yìí ni àwọn ologun ti wọn n ṣejọba lorilẹ-ede Mali ati Burkina Faso ti ṣeleri fun Ọgagun Tchiani Abdulrahmane, ti i ṣe olori awọn ọmọ ogun ilẹ Niger to gbajọba pe gbagbaagba lawọn wa lẹyin rẹ, awọn si ti ṣetan lati kun un lọwọ ti wọn ba fẹẹ kogun ja a.

Láti lè fi dá wọn lójú, kí ọ̀kan àwọn Niger sì lè balẹ̀ pé lóòótọ́ ni ọrọ ti wọn n sọ, awọn ọmọ ogun orilẹ-ede mejeeji yii ti lọọ pagọ fun awọn ọmọ ogun wọn niluu Niamey, ti i ṣe olu ilu orileede Niger, lati ṣatilẹyin fawọn ọmọ ogun wọn.

Bákan náà ni Abdulrahmane tó lé Ààrẹ Bazoum kúrò lórí ipò ti bẹbẹ fún atilẹyin àwọn Wagner tẹlẹ, Prigozhin tí í ṣe olórí ikọ náà si ti fi i lọkan balẹ.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orí ilẹ̀ Mali ti ko jinna pupọ si Niger lawọn ọmọ ogun Wagner ṣi wa, igbagbọ awọn eeyan ni pe wọn ko duro sibẹ lasan, nitori ati le ran Niger lọwọ ti ogun ECOWAS ba fẹẹ ja wọn ni.

Tẹ ò bá gbàgbé, latigba tàwọn ológun ti gbàjọba ilẹ̀ Niger lóṣu tó kọjá, làwọn àjọ ECOWAS ti n wa gbogbo ọna lati da ijọba alagbada pada sori ipo niluu naa. Ṣugbọn to jẹ pe gbogbo igbesẹ ti wọn n gbe ni ko ti i ni ojutuu, nitori gbogbo ẹbẹ ti wọn n bẹ lo n bọ sẹyin eti ijọba ologun Niger, nigba ti wọn si ni ogun lo ku tawọn yoo fi yanju ọrọ naa, ohùn ikilọ lawọn ologun ọhun fi ranṣẹ pe ti wọn ba dan an wo, igbesẹ tawọn naa yoo ya wọn lẹnu.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣìíríṣìí ìmọràn ló ń wọlé fún Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu tí i ṣe olórí ECOWAS, láti má ṣe fi ogun yanjú ọrọ̀ náà, àwọn èèyàn ilẹ̀ Niger kò dìgbà kankan túra sílẹ̀ láti ìgbà tí wọ́n ti ń lérí ogun sí wọn, àwọn orílẹ-èdè alámùúlétì wọn àtàwọn ọmọ ogun aládàáni ilẹ̀ Russia ti wọ́n ń pè ní Wagner yìí náà sì ti ní kí wọ́n máa jó lọ, nítorí bí i iké làwọn làwọn lẹ́yìn wọn.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *