Ìsèjọba tí kò dára ló fàá tí àwọn ọmọ wa se ń JA PA – Charly Boy
Mary Fagbohun
Olorin, Charles Oputa, ti a mo si Charly Boy, ti so pe awon eniyan n kuro ni Naijiria lo si ile okeere nitori isejoba ti ko dara ni orile ede yi.
Irohin jade pe Naijiria n dojuko orisirisi nnkan to n se okunfa idinkun opolo pipe ni orile ede yi nitori bi ogooro awon ojogbon se n ko lo si ile Europe ati Ariwa Amerika ni ona lati wa ibi ti ile ti deju.
Nigba to fi fonran ogunlogo odomode olubewe to peju si gbagede ti a ti n bewe fun iwe irinna lo si Uk (UK Visa Application Centre, TSL) ni Ikeja, Eko, lede laipe yi, Charly Boy kedun bi ogooro olopolo pipe se n fi orile ede yi sile.
O fi oro ifori sori fonran naa pe, “Gbagede ti a ti n gba iwe irinna lo si UK (UK Visa Application Centre, TSL) Ikeja ni Eko lana.
“Awon ojogbon wa to dara ju n fi ipago ti a ko yi sile.
“Bi a se fi aaye gba eyi to buru ju lara wa lati dari eyi to dara ju lara wa.”

