llé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó kọ̀ láti fi òǹtẹẹ̀ lu àwọn orúkọ kan fún ipò Kọmísọ́nà

llé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó kọ̀ láti fi òǹtẹẹ̀ lu àwọn orúkọ kan fún ipò Kọmísọ́nà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó lọ́jọ́rú kọ̀ jálẹ̀ láti fòntẹ̀ lu ìyànsípò àwọn Kọmísọ́nà tẹ́lẹ̀ tí Gómìnà Babajide Sanwo-Olu fàkalẹ̀ fún àyẹ̀wò.

Àwọn Kọmísọ́nà tẹ́lẹ̀ náà ni Gbenga Omotoso, Akin Abayomi àti Sam Egube.

Àwọn yòókù ni Cecila Dada, Olalere Odusote àti Folashade Adefisayo.

Orúkọ àwọn wọ̀nyí ló wà lára orúkọ Kọmísọ́nà tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó dápadà fún Gómìnà.

Orúkọ àwọn wọ̀nyí ló wà lára orúkọ Kọmísọ́nà tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó dápadà fún Gómìnà.

Èyí ló wà nínú àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó, Bisola Branco Adekola buwọ́lù fún àwọn akọ̀ròyìn.

Ìdá àádọta àwọn tí wọ́n dápadà ló ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Gómìnà Babajide Sanwo-Olu ní sáà tó lọ.

Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó, Rt Hon Mudashiru Obasa ni ìgbésẹ̀ ilé ló dá lé lórí àyẹ̀wò tí ẹ̀ka ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin tó ń rísí àyẹ̀wò síse tí Akójàánu ilé, Fatia Mojeeb léwájú rẹ̀.

Abẹnugan ilé wá kan sáárá sí ẹ̀ka fún isẹ́ takuntakun, tó sí tún rọ àwọn Kọmísọ́nà ti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin buwọ́lù láti rí i dájú pé àwọn sin aráàlú ní ìlànà tó bá òfin mu.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *