Ẹ mójútó ṣẹ́ ni o, ọmọ Nàìjíríà ò fẹ́ gbọ́ àwáwí. Tinubu pàrọwà sáwọn Mínísítà

Ẹ mójútó ṣẹ́ ni o, ọmọ Nàìjíríà ò fẹ́ gbọ́ àwáwí. Tinubu pàrọwà sáwọn Mínísítà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà ní ìrètí pipẹ àárẹ̀ tó gbópọn ní-ín dá sínú ọkàn onírètí.
“Èmi ni awakọ̀, gbogbo àwọn ọmọ Naijiria ni wọn jókòó sí ẹ̀yìn mi ti wọ́n si n wòye bí èmi àti yín ṣe n tukọ̀ yii.Àwọn sì ni èrò ọkọ̀ yìí”

Ọ̀rọ̀ tí Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Bọla Ahmed Tinubu sọ fún àwọn Mínísítà tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ búra fún gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìgbìmọ̀ ìṣèjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ààrẹ Tinubu ní gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ń retí ìgbésẹ akin èyí tí yóó mú ìrètí ọ̀tun tí ìṣèjọba òun dúró lé lórí jáde.

Ó ní gbogbo àwọn Mínísítà yìí ló ní ipa láti kó lọ́nà àti rí pé gbogbo ìlérí wọ̀nyí bọ́ síi fún wọn.

Ó ní gbogbo àwọn Mínísítà náà gbọdọ̀ mọ̀ pé àwọn kìí ṣe Mínísítà agbègbè kóówá wọn tàbí ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti wá bíkòṣe aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lápapọ̀.

Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ṣètò ìbúra fún àwọn Mínísítà tuntun fún ìgbìmọ̀ ìṣàkóso ìjọba àpapọ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn lọ́jọ́ Ajé.

Àwọn Mínísítà marundinlaadọta ní Aàrẹ búra fún ní gbọ̀ngán ìgbàlejò nlá tó wà ní ilé Ààrẹ ní Aso Rock Villa nílùú Abuja.

Àwọn Mínísítà tí wọ́n búra fún lọjọ Ajé rèé:

Mínísítà fún ọ̀rọ̀ abẹ́lé, Bunmi Tunji-Ojo
Mínísítà fún ibanisọrọ, ọgbọn inu ati ọrọ̀ ajé ìgbàlódé, Bosun Tijani
Mínísítà fún ètò ìṣúná àti ọrọ̀ ajé, Wale Edun
Mínísítà fún ọrọ ajé inú omi, , Adegboyega Oyetola
Mínísítà fún ohun àmúṣagbára, Adedayo Adelabu
Mínísítà Kejì fún ètò ìlera àti ìgbáyégbádùn aráàlú Tunisia Alausa
Mínísítà fún ìdàgbàsókè òhun àlùmọ́nì ilẹ̀, Dele Alake
Mínísítà fún ìrìnàjò afẹ́, Lola Ade-John
Mínísítà fún ìdálẹ́ṣẹsílẹ̀, kátàkárà àti ìdókoòwò, Doris Anite
Mínísítà fún ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ, Uche Nnaji
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́ àti ìgbanisíṣẹ́, Nkiruka Onyejeocha
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin, Uju Kennedy
Mínísítà fún iṣẹ́ òde, David Umahi
Mínísítà fún ìdàgbàsókè ẹkùn Niger Delta, Abubakar Momoh
Mínísítà fún ètò ìgbógun ti ìṣẹ́, Betta Edu
Mínísítà fún ìdàgbàsókè afẹ́fẹ́ gáàsì, Ekperikpe Ekpo
Mínísítà fún epo rọ̀bì, Heineken Lokpobiri
Mínísítà fún ìrìnnà òfurufú Festus Keyamo
Mínísítà fún eré ìdárayá, John Enoh
Mínísítà fún olú ìlú Nàìjíríà, Nyesom Wike
Mínísítà fún àṣà, ìṣe àti ọ̀rọ̀ ajé ẹbùn ọpọlọ, Hannatu Musawa
Mínísítà ètò àbò, Mohammed Badaru
Mínísítà Kejì fún ètò àbò, Bello Matawalle
Mínísítà kejì fún ètò ẹ̀kọ́, Yusuf T. Sunumu
Mínísítà fún iléègbé àti ìdàgbàsókè ìlú, Ahmed M. Dangiwa
Mínísítà kejì iléègbé àti ìdàgbàsókè ìlú, Abdullah T. Gwarzo
Mínísítà fún àtò ọrọ̀ ajé, Atiku Bagudu
Mínísítà kejì fún olú ìlú Nàìjíríà, Mairiga Mahmud
Mínísítà kejì fún ìpèsè omi àti ìmọ́tótó àyíká, Bello M. Goronyo
Mínísítà fétò Ọ̀gbìn àti ìpèsè oúnjẹ, Abubakar Kyar
Mínísítà fétò ẹ̀kọ́, Tahir Maman
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè, Yusuf M. Tuggar
Mínísítà fún ètò ìlera, Ali Pate
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́pàá, Ibrahim Geidam
Mínísítà kejì fún ìdàgbàsókè irin tútù, U. Maigari Ahmadu
Mínísítà fún ìdàgbàsókè irin tútù, Shuaibu A. Audu
Mínísítà fún ètò ìròyìn, Muhammed Idris
Agbẹjọ́rò àgbà àti Mínísítà fún ètò ìdájọ́, Lateef Fagbemi
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́ àti ìgbanisíṣẹ́, Simon B. Lalong
Mínísítà kejì fún àwọn ọlọ́pàá, Imaan Sulaiman-Ibrahim
Mínísítà fún àkànṣe iṣẹ́ àti ajọṣepọ àwọn ẹ̀ka ìjọba, Zephaniah Jisalo
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ omi àti ìmọ́tótó àyíká, Joseph Utsev
Mínísítà kejì fún ètò ọ̀gbin àti ìpèsè oúnjẹ, Aliyu Sabi Abdullahi

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *