August 2024

Ò̩wó̩n epo!

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ò̩wó̩n epo! Àwọn ọ̀dọ́ ìlú Ipokia fárígá fún ilé-iṣẹ́ aṣọ́bodè, gbèdèke ọjọ́ mẹ́rìnlá péré

Ẹgbẹ́ kan, Ipokia Local Government Youth Forum (IPYF), ti fi ẹsun kan ilé-iṣẹ́ aṣọ́bodè ilẹ̀ Nàìjíríà, Nigeria Customs Service (NSC), pé wọ́n ń gbé epo tó yẹ fún àwọn èèyàn Ipokia lọ tà ní orílẹ-èdè Benin.

Ẹgbẹ IPYF ṣọ pe eyi ko jẹ ki awọn eeyan ri epo ra ni awọn ile epo ni gbogbo ijọba ibilẹ Ipokia.

Wọn ni idaamu gidi ati owo gọbọi ni wọn fi n ra epo bẹntiroolu lọwọ awọn to n ta a lọja okunkun (Black market).

Koda, gbedeke ọsẹ meji pere ni ẹgbẹ naa sọ pe awọn fun ileeṣẹ aṣọbode Naijiria lati dẹkun bi wọn ṣe ni wọn n gbe epo to yẹ fun Ipokia lọọ ta ni ibomiran.

Wọn ni bi inira airi epo ra ti awọn n koju ba fi tẹsiwaju lẹyin ọsẹ meji, nitori bi awọn oṣiṣẹ aṣọbode ṣe n gbabọde, awọn yoo ti gbogbo ilu pa ni.

Ṣaaju ni ẹgbẹ yii ti kọkọ fi lẹta kan ṣọwọ si ọga agba ileeṣẹ aṣọbọde Naijiria, Bashir Adewale, eyi ti Alaga wọn, Imoleayo Mawutin Deji, buwọlu lorukọ ẹgbẹ.

Ninu lẹta naa ni wọn ti ṣalaye pe ọdun 2019 ni ijọba ti ṣofin awọn oniṣowo epo ko gbọdọ ta epo ni ijọba ibilẹ Ipokia.

Eyi mu ki awọn araalu o maa rin irin ogun kilomita si ilu naa, ki wọn to o ri epo ra.

Ija ti araalu ja lo mu ki ijọba pada fi aaye gba ileepo mẹrin lati maa ta epo fun wọn laarin ilu.

Ṣugbọn wọn ko ta a fun araalu, afi fun awọn ti wọn n ta a si Benin.

Gẹ́gẹ́ bí Alága ẹgbẹ́ ọdọ ìjọba ìbílẹ̀ Ipokia ṣe wí, ó ní láàrin ọsẹ méjì yíì, kawọn Aṣọbode ṣe atunyẹwo epo 20km ti wọn n ṣe fún Ipokia.

Ki wọn mojuto awọn ileepo, lati ri i pe wọn n ta a fawọn eeyan.

O ni bi wọn ko ba le ṣe eyi, ki wọn kuku ti gbogbo ile epo to wa nijọba ibilẹ Ipokia pa.

‘’Ooṣa bo o ba le gbe mi, ṣe mi bi o ṣe ba mi.

‘’Lẹyin ọsẹ meji ti a fun wọn yii, bi wọn ko ba ti da wa lohun, gbogbo ijọba ibilẹ Ipokia ati Ogun West ni awa ọdọ maa tipa.

‘’Ati oṣiṣẹ aṣọbode o, ati ọlọpaa o, a o ni i jẹ ki ohunkohun ṣiṣẹ, a maa ti i pa a ni, afi ti wọn ba da awọn eeyan wa lohun. A o si ni i yi ipinnu wa yii pada o, iya yii ti pọju.’’

Ìgbìyànjú wa láti bá àjọ Aṣọbode ilẹ̀ wa sọrọ ló já sí pàbó.

Ajaero wá á wí tẹnu rẹ,Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá pe ààrẹ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC fún onírúurú ìwà ọ̀daràn

Ajaero wá á wí tẹnu rẹ,Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá pe ààrẹ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC fún onírúurú ìwà ọ̀daràn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá orílẹ̀ yìí ti kọ̀wé ránṣẹ́ pe Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, NLC, Joe Ajaero lori ẹ̀sùn ṣíṣe agbátẹrù àwọn agbébọn, aṣekúpani.

Yatọ si ṣiṣe agbatẹru awọn agbebọn, ọlọpaa tun sọ pe Ajaero lọwọ ninu iwa jibiti ori ayelura ati oniruuru iwa ọdaran miran.

Iwe ipe ti wọn kọ ranṣẹ si Ajaero lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024, eyi ti igbakeji ọga ọlọpaa lẹka PIR, ACP Adamu Muazu buwọ ni wọn ti sọ pe ki alaga NLC naa wa sọ tẹnu rẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe bi Ajaero ba kọ lati yọju si wọn gẹgẹ bi wọn ṣe fiwe pe e gẹgẹ bi ọmọluabi, awọn yoo fi kele ofin gbe e.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ ninu iwe ipe ti wọn fi ṣọwọ si Ajaero pe “ileeṣẹ ọlọpaa n ṣe iwadii lori ẹsun gbigbimọ iwa ọdaran, ṣiṣagbatẹru agbebọn, iwa ọdaran nla, igbimọ ọtẹ, lilo ipo lọna aitọ, ati jibiti ori ayelujara, eyi ti wọn ti darukọ rẹ.”

Ọlọpaa sọ pe Ajaero ni lati yọju si ọfiisi awọn logunjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 ni deedee agogo mẹwaa owurọ, ni Abuja.

Ileeṣẹ ọlọpaa tun fidi rẹ mulẹ pe Ajaero ni lati mọ daju pe bi o ba kọ lati bọwọn fun iwe-ipe naa, kele ofin lawọn yoo fi gbe e janto.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC funra rẹ ti wa jẹ ko di mimọ pe lotitọ lawọn gba iwe-ipe naa lati pe alaga apapọ wọn, ati pe bi wọn ṣe pe Ajaero ko ṣẹyin bawọn ọlọpaa ṣe wa kọlu ileeṣẹ awọn.

Ninu atẹjade ti alakoso eto iroyin fun ẹgbẹ NLC, Benson Upah gbe jade, o sọ pe ejo lọwọ ninu.

“O foju han pe, a ko tii gbọ ohun to gbẹyin nipa bi wọn ṣe wa kọlu olu-ileeṣẹ NLC,” Upah lo sọ bẹẹ.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ bu ẹnu atẹ lu ileeṣẹ ọlọpaa lori awọn to farapa lasiko iwọde ‘ebi n pa wa’ to lọ.

Ẹwẹ, igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ, NEC ti pe ipade pajawiri lori bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe ni ki Ajaero wa sọ tẹnu rẹ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

Laarọ ọjọ Iṣẹgun ni igbimọ NEC fi ipade pajawiri ọhun si eyi ti wọn ti kepe gbogbo awọn ti ọrọ kan lati wa nibi ipade naa.