Dẹ́rẹ́bà tó pa òṣìṣẹ́ LASTMA l’Ékòó wà ní gbaga agbófinró

Dẹ́rẹ́bà tó pa òṣìṣẹ́ LASTMA l’Ékòó wà ní gbaga agbófinró

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iwájú Onídàájọ́ Oyindamọla Ogala, ti ilé-ẹjọ́ gíga kan tó wà nílùú Ikeja, ní ìpínlẹ̀ Èkó, ni wọ́n wọ́ dẹ́rẹ́bà mọto akérò kan, Ọ̀gbẹ́ni Shokoya, lọ l’Ọ́jọ́bọ, ọjọ́ kẹrin, oṣù Keje, ọdún yìí. Ẹsùn táwọn agbófinró ìpínlẹ̀ Èkó fi kan olùjẹ́jọ́ náà ni pé lọ́jọ́kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kínní, ọdún 2012, ó fi mọ́tò akérò rẹ̀, Opel, tí nọ́mbà rẹ̀ jẹ́ AAA 74 GG, pa Olóògbé Akinmade Samson Ọlawale, tó jẹ́ òṣìṣẹ́ àjọ tó ń rí sí ìgbòkègbodò ọkọ́ lójú títí ní ìpínlẹ̀ Èkó ‘Lagos State Traffic Management Agency’ LASTMA, l’Ópòópónà Demurin, lágbègbè Mile 12, níjọba ìbílẹ̀ ìdàgbàsókè Agboyi-Ketu, ní ìpínlẹ̀ Èkó. Ìwà tó hù ọ̀hún ni wọ́n ló lòdì sófin, tó sì ní ìjìyà lábẹ́ òfin ìpínlẹ̀ Èkó.

Lásìkò ti igbẹjọ ọhún wáyé nípa ẹsùn ti wọn fi kan an nile-ẹjọ lọjọ Tọsidee, ẹlẹrii ti agbefọba ijọba ipinlẹ Eko pe sita, Abilekọ Aderonkẹ Malik, sọrọ ta ko olujẹjọ nile-ẹjọ naa pe o mọ-ọn-mọ fi mọto rẹ pa oloogbe naa ni, nitori pe lasiko ti eṣu n gbọwọ rẹ lo lọwọ, oloogbe naa n bẹ ẹ pe ko ma fi mọto naa tẹ oun pa, ṣugbọn ti ko gba.

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2021, ni wọn kọkọ foju olujẹjọ bale-ẹjọ naa, to si sọ pe oun ko jẹbi rara lori ẹsun ti wọn fi kan oun, eyi lo mu ki adajọ sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹrin, oṣu Keje, ọdun yii.

Lasiko to n gbe idajọ rẹ kalẹ, adajọ gboṣuba nla fun awọn agbefọba ipinlẹ Eko fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe nipa ẹjọ naa.

O ni pẹlu gbogbo ẹri to wa niwaju oun, ko si awijare kankan fun olujẹjọ nipa ẹsun ti wọn fi kan an.

Lẹyin gbogbo atotonu, adajọ ju dẹrẹba ọhun sẹwọn ọdun mejila pẹlu iṣẹ aṣekara lọgba ẹwọn Kirikiri, l’Ekoo.