Kò sáàyè fáwọn tó bá fẹ́ dá wàhálà Yoruba Nation sílẹ̀ l’Ọ́ṣun o – Adeleke
Kò sáàyè fáwọn tó bá fẹ́ dá wàhálà Yoruba Nation sílẹ̀ l’Ọ́ṣun o – Adeleke
Fẹ́mi Akínṣọlá
Gómìnà Ademọla Adeleke ti ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti gbé àwọn ẹṣọ́ ààbò dìde láti tako àwọn ajijangbara fún idasilẹ òmìnira ilẹ̀ Yorùbá, èyí tí àwọn olóyìnbó ń pè ní ‘Yoruba Nation Agigators’.
Bí ẹ kò bá gbàgbé, láìpẹ́ yìí ni àwọn ajìjàgbara yawọ ilé iṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nínú aṣọ̀kan ologun, nibi ti ewọn ti lọ da wahala nla silẹ, ṣugbọn ti ọwọ ọlọpaa pada tẹ awọn ti ko dini ni ogun.
Ṣùgbọ́n láti lè dẹ́kun irú ìṣẹlẹ̀ yìí ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Gómìnà Adeleke ti pàṣẹ fún oludamọran pàtàkì lórí ọrọ̀ ètò aabọ, Samuel Ojo láti dìde sí ọrọ̀ náà
Adeleke ní òun kò lajú sílẹ̀ láti jẹ́ kí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tún ṣẹlẹ̀ níbi tóun ti jẹ́ Gómìnà, fún ìdí èyí, ó ní àwọn elétò ààbò dúró digbí ní ìgbaradì sí ilé iṣẹ ìjọba ìpínlẹ̀ náà.
Bákan náà ló tún ní kí àwọn elétò lọ dáàbò bo ilé iṣẹ igbohun sáfẹ́fẹ́ ti ìpínlẹ̀ náà, ìyẹn Osun State Broadcasting Corporation (OSBC), èyí tó ni ó ṣeé ṣe kí àwọn ajìjàgbara náà kọlù.
A gbọ́ pé láti ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọsẹ tó kọjá yìí làwọn elétò ààbò ti lọ dúró sí àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba àti gbogbo ibi tí ìjọba ní dúkìá tó jọjú sí nílùú Òṣogbo fún ètò ààbò tó péye.
Adeleke ti wá gba àwọn èèyàn lámọran láti lo ìfẹ, ìṣọ̀kan àti láti jẹ́ kí àlàáfíà jọba lásìkò yìí.
O ni dipo ki awọn ajijangbara maa pe fun idasilẹ orileede Yoruba, ki wọn gbajumọ bi atunṣe yoo ṣe tubọ deba iwe ofin orileede yii, eyi ti yoo ro awọn ipinlẹ lagbara nipa ojuṣe wọn.
Bákan náà ló fi kún ọrọ̀ rẹ̀ pé wàhálà kò lè yanjú ìṣòro orílẹ-èdè yìí, bí kò ṣe ìjíròrò àti àpérò tó lọ ni ìbámu pẹ̀lú ìwé òfin, tó sì lóun nígbàgbọ́ pé àtúnṣe tó ń lọ lọwọ́ lórí ìwé òfin Nàìjíríà yóò tan iṣoro naa.
