October 2023

EFCC pe Afọbajẹ Ọ̀yọ́ méje lórí ẹ̀sùn gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fúnpò Alaafin tuntun

EFCC pe Afọbajẹ Ọ̀yọ́ méje lórí ẹ̀sùn gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fúnpò Alaafin tuntun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀kánjúà ń dàgbà ọgbọ́n inú ẹ̀ ń rewájú.
Àjọ tó ń gbógun ti ìwà àjẹbánu lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, EFCC sọ pé lóòótọ́ làwọn pe àwọn afọbajẹ Ìlú Ọ̀yọ́ kan láti wá dáhùn ìbéèrè nípa ẹsùn tí èèyàn kan fi kàn wọ́n.

Ẹsùn yí gẹ́gẹ́ bí EFCC ṣe sọ ní í ṣe pẹ̀lú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti yan Aláàfin Ọ̀yọ́ tuntun nínú àwọn tó díje dupò náà.

Agbẹnusọ àjọ náà Dele Oyewale ló fìdí ọ̀rọ̀ yí múlẹ̀ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwoò pẹ̀lú akọ̀ròyìn

Ó ní ọ́fìsì àwọn tó wà ní Ìbàdàn ló fi ìwé pe àwọn kan nínú àwọn afọbajẹ Ìlú Ọ̀yọ́ láti wá dáhùn ìbéèrè ẹ̀sùn àjẹbánu tí olùpẹ̀jọ́ kan fi kàn wọ́n.

”Àwọn méje la fi ìwé pè, méjì nínú wọn sì dáhùn ìpè wa tí wọ́n sì ti wí tẹnu wọn”

Dele Oyewale sọ pé àjọ ọ̀hún kò lè dárúkọ àwọn tó fi ẹsùn kan àwọn afọbajẹ yìí.

Bẹ́ẹ̀ ló sì ní àwọn kò tún lè dárúkọ àwọn tí àwọn fìwé pé nínú àwọn afọbajẹ náà.

”Kò sí nínú ìlànà wa láti dárúkọ wọn. A kò sì tún lè sọ olùdíje tí wọ́n fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n gba owó lọ́wọ́ rẹ”

Ọjọ́ kẹtàlélógún, osù kẹrin, ọdún 2022 ni Ọba Atanda Olayiwola Adeyemi wàjà.

Ó lo ọdún méjìléláàdọ́ta lórí àléfà kó tó wàjà.

Láti ìgbà tó ti papòdà ni àwọn tó ń díje dupò náà ti ń kópa nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lọ́dọ̀ àwọn Ọ̀yọ́ Mèsì tó ń ṣètò ẹni tí yóó di Aláàfin tuntun.
Mọ́kàndínláàdọ́rù-ún làwọn tó ń du ipò yí.

Fọ́nrán ìhòòhò mi lórí ayélujára kò sẹ̀yìn ọkọ àfẹ́sọ́nà mi- Moyo Lawal

Fọ́nrán ìhòòhò mi lórí ayélujára kò sẹ̀yìn ọkọ àfẹ́sọ́nà mi- Moyo Lawal

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ìṣẹ̀lẹ̀ kan ní-ín fi í kọ́gbọ́n ẹ̀dá láyé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò dá a tó kì ẹ̀dá fi ọ̀rọ̀ araarẹ̀ kọ́gbọ́n.
Ní báyìí, gbajúgbajà òṣèré tíátà, Moyo Lawal ti sọ̀rọ̀ síta lórí fọ́nrán kan tó wà lórí ayélujára èyí tó sàfihàn ìhòòhò rẹ̀ àti ìbálòpọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ọkùnrin kan.

Lawal ṣàlàyé pé ọkọ àfẹ́sọ́nà òhun tẹ́lẹ̀ ni ọkùnrin tó gbé fọ́nrán náà síta sórí ayélujára.

“Mo fẹ́ jẹ́ kó di mímọ̀ pé fọ́nrán kan tí mo ṣe pẹ̀lú ọkọ àfẹ́sọ́nà mi tẹlẹ kìí se nǹkan tó yẹ kó bọ sórí ayélujára àti pé ìgbésẹ̀ yìí tàbùkù sí mi “

Nínú ọ̀rọ̀ tó gbé sórí ayélujára, ó ṣàlàyé bí nǹkan ṣe lọ lẹ́yìn tí fọ́nrán náà bọ́ sí orí ayélujára.

“Nǹkan tí mo lè sọ fún yín tó dá mi lójú ni pé nǹkan kò yẹ kó rí bó se rí. Ẹẹméjì péré ni mó ní ìbáṣepọ̀ lọdun tó kọjá, ẹyọ kan níbẹ̀ ní fọ́nrán tó bọ sórí ayélujára

“Mo gbà kó ya fọ́nrán yìí nítorí mo mọ̀ pé kò gbé lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

“Ó ṣiṣẹ́ kárakára láti jẹ́ kí ń fi ọkàn tán òhun fún ọpọlọpọ ọdún tó jẹ́ pé a ti jọ lérò láti ra ilé, ṣe ìgbéyàwó àti àwọn nǹkan míì.”

Lawal tún mẹnubọ ọrọ̀ kan tó wà lórí ayélujára pé òun gan gan ló gbé fọ́nrán náà jáde.

“Fún àwọn tó ní èmi ni mo mọ̀ mọ̀ gbé fọ́nrán náà jáde, n ko ní nnkan tí mo fẹ sọ fun yin.

“Wọ́n ní nnkan tí kò bá pa èèyàn máa mú èèyàn lágbára síi ni. Gbogbo àwọn tó ṣe èyi, mo fẹ́ sọ fún yín pé n kò tíì sọ ìrètí nù. Mo dúró digbí “

Lórí ìṣòro Nàìjíríà, Ọkọ ọ̀ mi kì í ṣe òpìdán, àmọ́ yóó gbìyánjú —Oluremi Tinubu

Lórí ìṣòro Nàìjíríà, Ọkọ ọ̀ mi kì í ṣe òpìdán, àmọ́ yóó gbìyánjú —Oluremi Tinubu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ìwọ̀n oníwọ̀n la kìí mọ̀, ó yẹ kí á mọ tẹni.
Aya Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Sẹ́nẹ́tọ̀ Olurẹmi Tinubu sọ pé ọkọ òun Ààrẹ Bọla Tinubu kìí ṣe pidán-pidán, ṣùgbón ó ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ láti jẹ́ kí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà padà bọ̀ sípò.

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ ni ilé ìjosìn kan níbi tí wọ́n ti n ṣe ayẹyẹ àyájọ́ ọdún òmìnira ní ìlú Abuja lánàá ọjọ́ Àìkú, Olurẹmi sọ pé ọkọ òun kò ní dẹ̀bi ohun tó bàjẹ́ ní Naijiria ru àwọn tó ti ṣe ìjọba sẹ́yìn.

Àmọ́ṣá, Oluremi ní ìjọba Tinubu yóó tún gbogbo ohun tó ti bàjẹ́ ṣe, àti pé yóó mú ìrọ̀rùn bá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíría .

Ó fikún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun ní ìgbàgbọ̀ nínú ọkọ òun pé ó máa ṣiṣẹ́ láti ríi pé àlàáfíà yóó fi jọba ni Nàìjíríà.

Sẹ́nẹ́tọ̀ Oluremi tún sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ọjọ́ ọ̀la sì ń bọ̀ wá dára lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ìgbà ọ̀pọ̀ ti dé ní Nàìjíríà, nítorí náà, àwọn ọmọ Nàìjíríà gbọdọ̀ rí ju ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ báyìí lọ tí wọ́n bá fẹ́ jẹ́ alábàápín nínú ìgbéga orílẹ-èdè wọn.

Ó sì tún rọ àwọn ọmọ orílẹ-èdè Nàìjíríà láti ṣe àjọyọ òmìnira ní ìṣọ̀kan èyí tó ń gbé orílẹ-èdè lékè.

”Kò sí ìdojúkọ tí a kò lè borí tí a bá lè tẹ lé ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ nínú ìwé mímọ́ pé ẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ tí a di ẹrù wúwo lé lórí, emi ó sì fi ìsinmi fún ọkàn yín.

Ní irú àsìkò báyìí, gbogbo ohun tí a lè ṣe ni láti di ìgbàgbọ́ wa mú sinsin nínú Ọlọ́run.

Aya Ààrẹ tún fi dá àwọn ọmọ orílẹ-èdè Nàìjíríà lójú pé Tinubu ti ké sí àwọn orílẹ̀-èdè lágbayé láti wá dá ilé iṣẹ́ sílẹ̀ fún ìrọ̀rún gbogbo èèyàn,” Olurẹmi sọ bẹ́ẹ̀.

Ìdí tí mo fi ń di irun mi – Adekunle Gold

Ìdí tí mo fi ń di irun mi – Adekunle Gold

Mary Fágbohùn

Olorin Naijiria, Adekunle Kosoko, ti a mo si Adekunle Gold, ti safihan pe didi irun oun kii se fun ti ise.

O wi pe oun di irun oun nitori pe oun fe gbiyanju nnkan to yato wo.

Olorin ‘Party No Dey Stop’ naa safihan eyi nigba to farahan bii alejo lori eto mohunmaworan MTV Base Africa, Touching Base, ti osere tiata Susan Pwajok se atokun re.

O wi pe, “Ko si eto fun [ara didi irun] bii ise.

“Ni 2019, irun mi n gun. E ranti igba ti mo ni irun to ga. Mo wa so pe, ki n gbiyanju ara miran. E je ki n gbiyanju lati mu ki irun yi gun ki n si se e. Mo si ni ile irun to dara, tabi ohunkohun ti e ba pe. Ile irun to dara [o rerin].

“Sugbon, bee ni. Mo kan pinnu lati mu ki o gun ni mo si ri pe o dara lori mi.”