Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ OAU fárígábí àlékún ṣe bá owó ilé ẹ̀kọ́ wọn
Ara ò rokùn ara ò rọ
adìyẹ lọ̀rọ̀ dà báyìí o, bí
àwọn aláṣẹ àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Obafemi Awolowo ti Ilé Ife, ìpínlẹ̀ Osun ti ń forígbárí báyìí nítorí bí àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ náà ṣe mú àlékún bá owó tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa sàn fún sáà tuntun tí wọ́n fẹ́ bẹ̀rẹ̀.

Ilé ẹ̀kọ́ náà mú àlékún bá iye owó tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń san tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé fún sáà ẹ̀kọ́ di N101,200 láti N28,100, tí àwọn tó sì ń padà sẹ́nu ẹ̀kọ́ yóò san N89,200 láti N20,100 tí wọ́n ń san tẹ́lẹ̀.
Agbẹnusọ OAU, Abiodun Olarewaju nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́rú ṣàlàyé pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní ẹ̀ka Faculties of Arts, Law àti Humanities yóò máa san N89,200 fún àwọn tó bá ń padà sẹ́nu ẹ̀kọ́ .
Ó ní àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé sílé ẹ̀kọ́ náà ní ẹ̀ka yìí yóò san N151,200 ní ọdún kan.
Olarewaju ní iye owó tuntun yìí ni ìgbìmọ̀ aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ buwọ́lù lẹ́yìn tí wọ́n ṣe ìpàdé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.
Àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀rọ àti sáyẹ́ǹsì yóò máa san N163,200 fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé, tí àwọn tó sì ń padà sẹ́nu ẹ̀kọ́ yóò máa san N101,200.
Bákan náà ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀ka College of Health Sciences àti Pharmacy yóò san N190,200 fún àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé tí àwọn tó ń padà sẹ́nu ẹ̀kọ́ yóò sì san N128,200.
Wọ́n ní gbogbo owó ló jẹ́ ti ọdún kan péré.
Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ iké ẹ̀kọ́ ọ̀hún ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ àwọn aláṣẹ wọn láti mú àlékún bá owọ ilé ẹ̀kọ́.
Àtẹ̀jáde kan tí ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà fi síta ní àwọn kò gba iye tí àwọn aláṣẹ náà ni àwọn yóò san nítorí wọn kò fi tó àwọn létí kí wọ́n tó mú àlékún bá owó náà.
Ààrẹ àti akọ̀wé SUG OAU, Abbas Ojo àti Akinboni Opeyemi nínú àtẹ̀jáde náà ní àwọn kò ní gba nǹkan tí àwọn aláṣẹ náà ṣe wọlé nítorí ìjọba àpapọ̀ ti sọ wí pé àwọn kò lọ́wọ́ nínú bí àwọn ilé ẹ̀kọ́ ṣe ń mú àlékún bá owó ilé ẹ̀kọ́.
Wọ́n ní gbogbo ìgbésẹ̀ ni àwọn máa gbé láti ri dájú pé àwọn aláṣẹ náà yí ìpinnu wọn padà àti pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tí àwọn máa fi rí ọ̀rọ̀ náà yanjú.