August 2023

Kò sí èrè kankan nínú ìsubú ò̩ré̩ e̩ni – Tonto Dikeh

Kò sí èrè kankan nínú ìsubú ò̩ré̩ e̩ni – Tonto Dikeh

Mary Fágbohùn

Onirawo fiimu teleri, Tonto Dikeh, ti so fun awon afenifere re idi ti won fi gbodo gbadura fun iserere ore won ju ibaje won lo.

O ni oun gbadun pinpin ninu wiwa ni ayika awon ore to ni owo, eni ti o (Tonto) so pe won n se iranlowo fun oun ni opo igba.

Dikeh dabaa pe ki awon eniyan to n gbadura fun isubu ore won ronu wo bi bee ko won a ni ipin ninu isubu naa.

Iya omo kan naa jeje lati maa ji ni ojoojumo ki o si maa gbadura fun awon to n se iranlowo fun n ju ki o lowo ninu sisoro abuku si won.

O wi pe: “Awon ore mi olowo lo n se iranlowo fun mi bayii. Bi o ba wu o gbadura fun isubu awon ore re.

“Ebi jo maa pa gbogbo yin ni.

“Mo so pe ki n gbadura fun awon oluranlowo mi.. To ba wu o maa se ofofo awon oluranlowo re ooo, EMI MAA GBADURA FUN WON. #imolara.”

Femi Adebayo fi páńpé̩ gbé o̩kùnrin tó ń se àfarapè fíìmù ‘Jagun Jagun’ láì gba àse̩

Femi Adebayo fi páńpé̩ gbé o̩kùnrin tó ń se àfarapè fíìmù ‘Jagun Jagun’ láì gba àse̩

Mary Fágbohùn

Osere tiata Naijiria, Femi Adebayo, ti fi panpe gbe okunrin ti eni kan ko mo fun sise afarape fiimu Yoruba re tuntun to sese gbe jade, ‘Jagun-Jagun’.

Nigba to fi aworan lede ni oju opo Instagram re, osere tiata naa so pe gbogbo awon to lowo si iru iwa bee ni won ti fi panpe gbe.

O ko pe, “NI KIAKIA: Ikilo lodi si Afarape. Afarape je iwa odaran to n hale mo pataki ile ise iseda wa. Awon kan ti bere si ni se afarape ise ife yi.

“Awon kan ni a ti mu gege bi o se wa ninu aworan yi, a si n gbiyanju laisinmi lati mu awon to ku ki a le se idajo won.

“Iwadii wa nii se pelu awon ti won n gba fonran naa ni ona ti ko ba ofin mu, fimo oju awe telegram.”

Irohin jade pe Femi Adebayo, ninu iforo-wani-lenu-wo to se laipe yi, safihan pe oun ta awon pupo dukia oun lati ri owo na fun agbejade ‘Jagun Jagun’, eyi to sapejuwe bii ise agbese ti owo tabua ba lo.

Ojoojúmó̩ ni èmi àti ìyàwó mi ń jà – Òsèré tíátà, Keppy Ekpenyong

Ojoojúmó̩ ni èmi àti ìyàwó mi ń jà – Òsèré tíátà, Keppy Ekpenyong

Mary Fágbohùn

Ogbontarigi osere tiata Naijiria, Keppy Ekpenyong, ti so pe oun ma n ba iyawo oun, Nyong Bassey Inyang ja “lojoojumo” sugbon sibe o je “ore timotimo” oun.

O sapejuwe re bii “orebinrin, ale, iya omo ati ore timotimo.”

O so pe nigba miran o ma n sun oun lati ba a ja.

Akoni osere naa safihan eyi ninu iforo-wani-lenu-wo kan to se laipe yi pelu atokun eto, Chude Jideonwo.

O wi pe, “O je orebinrin mi, ale mi, iya omo mi, ore timotimo ati iyawo mi. A si gbodo ja lojoojumo. Ma a wa ro pe, ‘Ki lo n se e? Se kii re o ni?’”

O ni bi won se n ba ara won da awada nigba gbogbo n se iranlowo fun idurosinsin igbeyawo won.

Tokotayo naa ti se igbeyawo fun bii odun mejilelogbon ti Olorun si bukun asopo won pelu omo meji.

Ekpenyong tun safihan ninu iforo-wani-lenu-wo naa pe “dida osere tiata wa lara ilepa aye mi to wa si imuse.”

Àwọn ológun kéde bíbọ́ sórí àlèéfà ìjọba ní Gabon

Àwọn ológun kéde bíbọ́ sórí àlèéfà ìjọba ní Gabon

Fẹ́mi Akínṣọla

Ń ṣe ni ọ̀rọ̀ ìdìtẹ̀gbàjọba láwọn ìlú kan nílẹ̀ Adúláwọ̀ wá n fojoojúmọ́ ràn mọ̀ ọ̀ bí iná pápá báyìí ni bí àwọn ọmọ ogun ní Gabon tí bọ sórí ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán pé àwọn ti gbàjọba orílẹ̀ èdè náà.

Wọ́n ní àwọn wọ́gilé èsì ìdìbò tó wáyé ní orílẹ̀ èdè náà lópin ọ̀sẹ̀ níbi tí wọ́n ti kéde Ààrẹ orílẹ̀ èdè ọ̀hún Ali Bongo pé òun ló jáwé olúborí.

Àjọ elétò ìdìbò orílẹ̀ èdè Gabon ní Bongo ló jáwé olúborí nínú ó dín díẹ̀ nínú ìdá méjì gbogbo ìdìbò tí wọ́n dì níbi ètò ìdìbò náà.

Ìdìtẹ̀gbàjọba yìí ni yóò fi òpin sí ọdún mẹ́tàléláàdọ́ta tí ẹbí Ali Bongo ti ń jẹ Ààrẹ Gabon.

Àwọn ọmọ ogún bíi méjìlá ló kó ara wọn jọ sórí amóhùnmáwòrán lọ́jọ́rú láti kéde pé àwọn ti wọ́gilé èsì ìdìbò náà àti pé gbogbo àwọn iléeṣẹ́ tó jẹ́ ti orílẹ̀ èdè náà ni àwọn ti fòfin dè.

Bákan náà ni wọ́n sọ wí pé gbogbo ẹnubodè tó wọ orílẹ̀ èdè ọ̀hún ni àwọn ti tì pa títí di ìgbà kan ná.

Tí ìdìtẹ̀gbàjọba yìí bá filè kẹ́sẹ járí, òhun ló máa jẹ́ ìdìtẹ̀gbàjọba kẹjọ tí yóò wáyé nílẹ̀ Adúláwọ̀ ní àwọn orílẹ̀ èdè tí ìjọba ilẹ̀ Faransé kó lẹ́rú.

Àwọn ológun náà ní àwọn wà lára ìgbìmọ̀ kan tó wà fún àtúntò orílẹ̀ èdè náà àti pé àwọn jẹ́ aṣojú àwọn ọmọ ogún orílẹ̀ èdè náà.

Ọ̀kan nínú àwọn ológun náà ní àwọn dìde láti dá ààbò bo àláfíà orílẹ̀ èdè Gabon nípa fífi òpin sí ìṣèjọba tó wà lóde èyí tó ti ń wakọ̀ orílẹ̀ èdè náà lọ sí oko ìparun.

Lẹ́yìn ìkéde yìí ni ìró ìbọn ń dún lákọlákọ ní olú ìlú orílẹ̀ èdè náà, Libreville.

Àwọn afọbajẹ Ìsẹ́yìn kéde Sefiu Oyebola gẹ́gẹ́ bíi Asẹ́yìn tuntun

Àwọn afọbajẹ Ìsẹ́yìn kéde Sefiu Oyebola gẹ́gẹ́ bíi Asẹ́yìn tuntun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn afọbajẹ ìlú Ìsẹ́yìn ti kéde ọba titun fún ipò Asẹ́yìn ti ìlú Ìsẹ́yìn.

Ọmọọba Ṣẹfiu Oyebọla ni wọ́n kéde gẹ́gẹ́ bí Asẹ́yìn tuntun.

Àwọn afọbajẹ ìlú Ìsẹ́yìn kéde Oyebọla gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóó bọ́ sípò ọba ìlú Ìsẹ́yìn ní ààfin asẹ́yìn lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ṣe sọ, àwọn afọbajẹ mẹ́wàá ló dìbò yan Ọmọọba Oyebọla sórí àpèrè Ọba ìlú náà.

Ẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́ta ní Ọmọọba Ṣẹfiu Oyebọla.

Àwọn ọmọọba méjìlá ló jáde du ipò asẹ́yìn lẹ́yìn tí Asẹ́yìn àná, Ọba Ganiyy Adekunle Ajínasẹ̀ .

Ó ti pé ọdún kan báyìí ti Asẹ́yìn Adekunle Ajínasẹ̀ wàjà ní ilé ìwòsàn ńlá UCH nílùú Ìbàdàn.

Ọdún márùndínlógún ló sì lò lórí oyè kò tó wọ káà ilẹ̀ sùn.

Níbáyìí, ohun tó kàn ni fún àwọn afọbajẹ láti fi orúkọ Asẹ́yìn tuntun tí wọ́n yan náà ṣọwọ́ sí Gómìnà Sèyí Mákindé àti ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fún ìgbàwọlé àti láti gba ọ̀pá àṣẹ.

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ní etí omi ìkìlọ̀ rè é o! – NEMA ṣèkìlọ̀

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ní etí omi ìkìlọ̀ rè é o! – NEMA ṣèkìlọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà ní a wí fúnni ká tó dáni, àgbà ìjàdkàdì ni. Wọ́n sì ní ó n bọ̀,ó n bọ̀, àwọ̀n láà dẹ ẹ́ dèé .
Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, NEMA ti ṣèkìlọ̀ pé ó ṣeéṣe kí omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù tún ṣọṣẹ́ gidigidi láìpẹ́ yìí nítorí bí orílẹ̀ èdè Cameroon ṣe fẹ́ ṣí omi odò Lagdo wọn sílẹ̀.

NEMA ní àwọn ìpínlẹ̀ tó wà ní bèbè omi odò Benue àti River ní ó ṣeéṣe kí àgbàrá náà ṣe ìjàmbá fún jùlọ tí wọ́n sì pàrọwà sí àwọn ènìyàn tó ń gbé létí odò náà láti kúrò níbẹ̀ lásìkò yìí.

Wọ́n ní ó kéré tán ìpínlẹ̀ mọ́kànlá bíi Adamawa, Taraba, Benue, Nasarawa, Kogi, Anambra, Edo, Delta, Bayelsa, Rivers àti Cross Rivers ni ó ṣeéṣe kí wọ́n fara kásá ìjàmbá omíyalé náà.

Ní ọdún tó kọjá, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àti dúkìá ló ṣòfò ní Nàìjíríà sọ́wọ́ omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù lẹ́yìn tí orílẹ̀ èdè Cameroon ṣí odò Ladgo kan náà sílẹ̀.

Dókítà Mustapha Habeeb tó jẹ́ adarí àjọ NEMA sọ fún akòròyìn pé àwọn aláṣẹ ní orílẹ̀ èdè Cameroon ti fi tó àwọn létí pé díẹ̀díẹ̀ ni àwọn yóò máa ṣí odò náà.

Dókítà Habbeb ní àwọn ti fi ìròyìn náà tó àwọn òṣìṣẹ́ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ Kogi, Benue àti Niger láti wà ní ìgbáradì dáadáa nítorí àwọn ni ọ̀rọ̀ yóò kọ́kọ́ kàn tí wọ́n bá ṣí odò náà.

Ó ṣàlàyé pé àwọn ti ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan tí ọ̀rọ̀ náà kan láti ṣàlàyé fún wọn ohun tí orílẹ̀èdè Cameroun sọ fún àwọn.

Ó ní lẹ́yìn náà ni òun tún sọ fún wọn níbi ìpàdé ìgbìmọ̀ aláṣẹ orílẹ̀èdè yìí láti gbáradì, kí wọ́n sì pèsè àmójútó tó péye sílẹ̀ kí odò náà má baà ṣe àkóbá tó lágbára fún àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ wọn.

Bákan náà ló ní òun gbà wọ́n ní ìmọ̀ràn láti pèsè ohun èlò láti mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan àti ní àwọn ẹkùn kọ̀ọ̀kan wọn.

Habeeb fi kún un pé àwọn gómìnà gbọ́dọ̀ ṣe àmójútó gbogbo ojúṣan àgbàrá wọn àti àwọn ibi tí omi ń gbà kọjá ní agb]egbè wọn kí ètò náà tó bẹ̀rẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ náà ní iléeṣẹ́ tó ń mójútó ọ̀rọ̀ omi àti ìmọ́tótó ti fi ìkọnilóminú hàn lórí bí odò River Benue ṣe ti kún ní àkúnjù tó sì rọ àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ tó wà ní agbègbè omi yìí láti tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá.

Ní ọdún tó kọjá àwọn aláṣẹ ní Nàìjíríà ní ó kéré tán ènìyàn 1,500 ló farapa, tí 500 mìíràn sì pàdánù ẹ̀mí wọn sí omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù ní Nàìjíríà.

Àwọn ènìyàn tó di aláìnílé lórí lọ́dún tó kọjá lé ní mílíọ̀nù kan lẹ́yìn tí Cameroon ṣí odò Lagdo ọ̀hún kan náà.

Àwọn ìpínlẹ̀ mọ́kànlá tó pààlà pẹ̀lú odò náà ni ó sì ti ṣe àkóbá fún lọ́pọ̀lọpọ̀.

Kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí NEMA yóò máa kìlọ̀ omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù fún àwọn ìpínlẹ̀ tí ó le ṣe àkóbá fún.

Ní oṣù Kọkànlá ọdún 2022 ni àjọ náà ti kọ́kọ́ kìlọ̀ pé omíyalé yóò pọ̀ ní àwọn ìpínlẹ̀ kan lọ́dún 2023 gẹ́gẹ́ bó ṣe wáyé lọ́dún 2022.

Wọ́n fẹ̀sùn kan pé àwọn ìpínlẹ̀ kan kò kọbi ara sí ìkìlọ̀ tí àwọn ṣe lórí ọ̀rọ̀ omíyalé náà.

Adarí NEMA, nígbà tó yọjú níwájú ìgbìmọ̀ àjọ tó ń rí sí àwọn àkàṣe iṣẹ́ kọminú pé gbogbo ìkílọ̀ tí àwọn ṣe fún àwọn ìpínlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2022 ni wọn kò múlò rárá.

Ó ní bí àwọn ìpínlẹ̀ náà ṣe kọtí ọ̀gbọ̀in sí àwọn ìpínlẹ̀ náà lọ ṣokùnfà bí omíyalé tó wáyé ní 2022 ṣe ṣàkóbá púpọ̀.

Ṣaájú ni NEMA ti ṣèkìlọ̀ pé àwọn ìpínlẹ̀ m;ejìlélọ́gbọ̀n máa rí ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù nítorí àyípadà ojú ọjọ́.

Mi ò mọ̀ pé ìwà ọ̀daràn ni kí èèyàn máa jí iná ìjọba lò…Afurasì kan

Mi ò mọ̀ pé ìwà ọ̀daràn ni kí èèyàn máa jí iná ìjọba lò…Afurasì kan

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọ́n ní ohun téèyàn ò mọ̀ ,dájúṣáká ó ṣàgbà èèyàn.
Ọmọkùnrin ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n kan, Abdulfatai Abdulateef, ti sọ pé tó bá jẹ́ pé òun mọ̀ pé ìwà ọ̀daràn tó níjìyà lábẹ̀ òfin ni jíjí iná lò ni, òun kò ní í ṣán irú àṣọ bẹ́ẹ̀ ṣorò.

Lateef àti ẹnì kejì rẹ̀, Adeṣina Ọpẹyẹmi, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n, ni ọwọ́ àjọ sífú dìfẹ́nsì ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun tẹ̀ láìpẹ̀ yìí lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ń jí iná ìjọba lò.

Nígbà tó ń ṣàfihàn wọn fún àwọn oníròyìn nílùú Òṣogbo l’Ọjọru, ọsẹ yìí, kọmandàǹtì àjọ náà, Sunday Agboọla, ṣàlàyé pé agbègbè Akéde, ni Oke-Baalẹ, nílùú Oṣogbo, lọwọ ti tẹ awọn mejeeji.

Agboọla ṣàlàyé pé lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, lawọn mejeeji yii gbimọ-pọ lati yọ waya kuro nidii mita ile ti wọn n gbe, ti wọn si bẹrẹ si i ji ina ìjọba lo.

Ó ní eléyìí ni wọ́n ń ṣe lọwọ́ tí ọwọ́ àwọn sifu difẹnsi pẹlu iranlọwọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ amunawa IBEDC fi tẹ wọn.

Nínú àwíjàre rẹ̀, Lateef ṣàlàyé fún akọ̀ròyìn wa pe bi owo ina ti awọn ba ra ṣe tete maa n tan lo fa a ti oun ati ẹni kẹji oun fi pinnu lati yara ji ina lo lọjọ naa.

Ó ní ẹ̀rọ omi (water pumping machine) lawọn fẹẹ lo lọjọ ti ọwọ tẹ awọn, ati pe igba akọkọ ti oun yoo ṣe iru nnkan bayii ri niyẹn, oun ko si mọ pe iwa ọdaran to le gbe oun de ọdọ awọn ẹṣọ alaabo ni.

Àmọ́ ṣá, Agboọla ti sọ pe awọn ọkunrin mejeeji yoo foju bale-ẹjọ nitori iwa to n ṣakoba fun eto ọrọ-aje orileede yii ni wọn hu.

Bákan náà ló ṣàfihàn Akinloye Abiọla, ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n, lórí ẹ̀sùn dída omi àláfíà agbègbè rú.

Abiọla ni wọ́n ní ó lọ máa ń fi ìgbà gbogbo dúnkookò mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ ìwakùsà kan nílùú Iléṣà.

Agboọla ṣàlàyé pé ní kété tíwàdíì bá ti parí ni Abiọla yóò fojú balé-ẹjọ́ láti sọ ohun tó rí lọ́bẹ̀ tó fi waro ọwọ́.

Àwọn ọmọ ogun Russia dé sí ẹ̀yìnkùlé Niger, láti ṣàtìlẹ́yìn fún wọn

Àwọn ọmọ ogun Russia dé sí ẹ̀yìnkùlé Niger, láti ṣàtìlẹ́yìn fún wọn

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ọ̀rọ̀ ìdìtẹ̀-gbàjọba àti ogun tó ṣeé ṣe kó bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn ológun tó gbàjọba orílẹ-èdè Niger, àti àjọ àwọn olórí orílẹ-èdè apá Ìwọ̀òrùn ilẹ̀ Áfríkà, Economic Community of West African States (ECOWAS), ti tún bá ọnà mí-ìn yọ pẹlú bí àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Russia ṣe ti dé sórílẹ̀-èdè Mali, láti ti àwọn Niger lẹ́yìn nítorí bí wọ́n ṣe fẹ́ ẹ́ dojú ìjà kọ wọn.

Olórí àwọn ikọ ọmọ ogun tí wọ́n ń pè ní Wagner yìí, ìyẹn Yevgeny Prigozhin, tó ti kọ́kọ́ lọ sí orílẹ-èdè Congo, ni wọ́n rí ní Mali laipẹ yìí nínú fídíò kan tó fi síta. Papaapa ló dì nínú aṣọ ológun rẹ̀, àlàyé tó sì ṣe ni pe awọn ko awọn ọmọ ogun lọ si Mali lati ba awọn ologun to n dari orile-ede naa koju awọn agbesunmọmi, atawọn ogun mi-in to n doju kọ wọn ni.

Ṣáájú àkókò yìí ni àwọn ologun ti wọn n ṣejọba lorilẹ-ede Mali ati Burkina Faso ti ṣeleri fun Ọgagun Tchiani Abdulrahmane, ti i ṣe olori awọn ọmọ ogun ilẹ Niger to gbajọba pe gbagbaagba lawọn wa lẹyin rẹ, awọn si ti ṣetan lati kun un lọwọ ti wọn ba fẹẹ kogun ja a.

Láti lè fi dá wọn lójú, kí ọ̀kan àwọn Niger sì lè balẹ̀ pé lóòótọ́ ni ọrọ ti wọn n sọ, awọn ọmọ ogun orilẹ-ede mejeeji yii ti lọọ pagọ fun awọn ọmọ ogun wọn niluu Niamey, ti i ṣe olu ilu orileede Niger, lati ṣatilẹyin fawọn ọmọ ogun wọn.

Bákan náà ni Abdulrahmane tó lé Ààrẹ Bazoum kúrò lórí ipò ti bẹbẹ fún atilẹyin àwọn Wagner tẹlẹ, Prigozhin tí í ṣe olórí ikọ náà si ti fi i lọkan balẹ.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orí ilẹ̀ Mali ti ko jinna pupọ si Niger lawọn ọmọ ogun Wagner ṣi wa, igbagbọ awọn eeyan ni pe wọn ko duro sibẹ lasan, nitori ati le ran Niger lọwọ ti ogun ECOWAS ba fẹẹ ja wọn ni.

Tẹ ò bá gbàgbé, latigba tàwọn ológun ti gbàjọba ilẹ̀ Niger lóṣu tó kọjá, làwọn àjọ ECOWAS ti n wa gbogbo ọna lati da ijọba alagbada pada sori ipo niluu naa. Ṣugbọn to jẹ pe gbogbo igbesẹ ti wọn n gbe ni ko ti i ni ojutuu, nitori gbogbo ẹbẹ ti wọn n bẹ lo n bọ sẹyin eti ijọba ologun Niger, nigba ti wọn si ni ogun lo ku tawọn yoo fi yanju ọrọ naa, ohùn ikilọ lawọn ologun ọhun fi ranṣẹ pe ti wọn ba dan an wo, igbesẹ tawọn naa yoo ya wọn lẹnu.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣìíríṣìí ìmọràn ló ń wọlé fún Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu tí i ṣe olórí ECOWAS, láti má ṣe fi ogun yanjú ọrọ̀ náà, àwọn èèyàn ilẹ̀ Niger kò dìgbà kankan túra sílẹ̀ láti ìgbà tí wọ́n ti ń lérí ogun sí wọn, àwọn orílẹ-èdè alámùúlétì wọn àtàwọn ọmọ ogun aládàáni ilẹ̀ Russia ti wọ́n ń pè ní Wagner yìí náà sì ti ní kí wọ́n máa jó lọ, nítorí bí i iké làwọn làwọn lẹ́yìn wọn.

Olamide kí o̩mo̩lé̩yìn rè̩, Asake kú oríire fún títa tíké̩è̩tì ìwo̩lé sí London O2 Arena tan

Olamide kí o̩mo̩lé̩yìn rè̩, Asake kú oríire fún títa tíké̩è̩tì ìwo̩lé sí London O2 Arena tan

Mary Fágbohùn

Asoro orin kiakia Naijiria ati oga ile ise orin, Olamide Adedeji, ti a mo si Olamide, ti ki omoleyin re, Asake, ku oriire fun tita gbogbo tikeeti iwole si gbagede to le e gba oke kan eniyan tan, O2 Arena ni London, United Kingdom.

Irohin jade pe Asake ta gbogbo tiketi iwole si gbagede akoni ni London tan ni ale ojo Aiku, ti o fi ni akosile ninu itan bii oje wewe Naijiria akoko lati se be e.

Olamide, Tiwa Savage, Fireboy ati ogooro awon olorin miran lo darapo mo Asake lori itage lati da awon eniyan laraya.

Ni oju opo Twitter re ni ojo Aiku, Olamide so pe aseyori Asake ya oun lenu lopolopo.

Oga YBNL naa ko o pe, “@asakemusik ku oriire Mr Mon£y! A dupe lowo Olorun fun ibukun to fi si ori akitiyan re.. o se opolopo nnkan to ya mi lenu gidi.”